Faith Adebọla, Eko
Ẹya ara ọkọ, agaga kinni kan to wa nibi agbari awọn ọkọ ode-oni ti wọn n pe ni Brain box, lawọn afurasi ole mẹrin yii n ji tu l’Ekoo, idi iṣẹẹbi wọn naa si lọwọ ti tẹ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, SP Benjamin Hundeyin, to sọrọ yii di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ṣe darukọ wọn, Sodiq Odugbade ati Aliyu Yusufa jẹ ẹni ogun ọdun, Aliaminu Ayinla, ẹni ọdun mọkanlelogun, nigba ti ẹni to kere ju laarin wọn, Ayọmide Ogunṣiyi, jẹ ẹni ọdun mejidinlogun pere.
Wọn ni ṣọọbu mẹkaniiki kan to wa lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi yii ti lọọ ji ẹya ara awọn ọkọ mẹsidiisi SUV mẹta tu, wọn tu Brain box awọn ọkọ naa, wọn tun ji oil pump ati awọn ẹya ara mi-in tu, wọn si sọ awọn ọkọ naa di koronfo, bẹẹ awọn kọsitọma mẹkaniiki ọhun ni wọn gbe ọkọ yii wa fun atunṣe.
Nigba ti wọn mu wọn, wọn jẹwọ pe loootọ lawọn ṣiṣẹẹbi naa, wọn ni niṣe lawọn ta awọn paati naa fawọn to n ta paati ọkọ, awọn si fowo ẹ ṣara rindin.
Alukoro ni wọn ti foju awọn afurasi naa bale-ẹjọ, wọn si rọ wọn da satimọle. O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan wọn, igbesẹ si n lọ lati wa awọn ti wọn taja ole naa fun lawari.