Ọmọọba ran awọn agbanipa si Kabiyesi Ọja-Ọdan

Gbenga Amọs, Ogun

Awọn afurasi ọdaran ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹfa tọwọ ba lagbegbe Ọja-Ọdan, nipinlẹ Ogun, ti jẹwọ pe iṣẹ iku ti wọn bẹ awọn lọwẹ ẹ lawọn fẹẹ jẹ fun Kabiyesi, Ọba ilu Gbokoto, wọn ni ọmọ bibi inu baba naa lo bẹ awọn lọwẹ, o si ti sanwo ẹmi bara rẹ fawọn, iyẹn lawọn ṣe fẹẹ yanju ẹ.

Orukọ awọn mẹfa tọwọ ba ọhun ni Michael Ayodele, Monday Samuel, Ademola Matthew, Hammed Jelili, Ogundele Ojeh ati Sunkanmi Fadina.

Gẹgẹ bii alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ni nnkan bii aago mẹrin kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn, nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, ta a wa yii, ni ọba alaye naa, G. O. Olukunle, Ọba ilu Gbokoto, tẹ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ọja-Ọdan, nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, laago, ipe pajawiri nipe ọhun, ọba naa ni kawọn ọlọpaa tete dide iranlọwọ, latari bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ṣe n dooyi yi aafin oun ka, o lo jọ pe wọn fẹẹ ṣiṣẹẹbi kan foun ni.

Lọgan ti DPO teṣan naa gbọrọ yii loun atawọn ẹmẹwa rẹ ti ta mọra, wọn si lọ saafin naa, wọn ba awọn afurasi apaayan naa loootọ, lọrọ ba di yinbọn si mi ki n yinbọn si ẹ laarin awọn ọlọpaa atawọn afurasi naa.

Nikẹyin, ọwọ ba mẹfa ninu wọn, awọn kan lara wọn si sa lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fara gbọta.

Nigba to de teṣan, awọn apaayan naa jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn, Ẹiyẹ ni wọn porukọ ẹgbẹ wọn, wọn lọmọ ọba naa lo waa ba awọn, to ṣalaye pe aawọ kan wa laarin ọba ati Olori ẹ to jẹ mama oun, aawọ naa le gidi, ohun toun si fẹ ni ki awọn ba oun gbẹmi ọba naa, o fawọn lowo, lawọn ṣe lọọ jiṣẹ naa.

Awọn ọlọpaa sare wa ọmọọba ti wọn darukọ yii lọ sile to n gbe, ṣugbọn ofo ọjọ keji ọja ni wọn ba, o ti na papa bora.

Lara awọn nnkan ija oloro ti wọn gba lọwọ awọn apaayan ọhun ni ibọn oloju meji kan, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin meji, ateyi ti wọn ti yin kan, ada, ati oogun abẹnu gọngọ. Wọn ni ọkan lara ibọn awọn wa lọwọ ọmọọba to sa lọ ọhun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki wọn fawọn afurasi oniṣẹ iku yii ṣọwọ sẹka awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to n ri si iwa ọdaran, ki wọn le ṣewadii to lọọrin lori ọrọ yii.

Bakan naa lo ni awari tobinrin n wa nnkan ọbẹ ni ki wọn fi ti ọmọọba to sa lọ naa ṣe, atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yooku.

Leave a Reply