Faith Adebọla
Ẹdun ọkan ati omije iya ibeji kan, Bilkisu Alhassan, ti pada di ayọ, nigba ti ọwọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tẹ obinrin to ji ọkan ninu awọn ibeji rẹ gbe ni wọọdu ọsibitu ti wọn tẹ wọn si, ti wọn si ri ọmọ naa gba pada lọwọ rẹ lọjọ kẹfa, o ni ẹsin tawọn eeyan n fi oun ṣe tori ipo agan toun wa lo jẹ koun dọgbọn buruku naa.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ta a wa yii, iyẹn ọjọ kẹjọ ti wọn ti bi awọn ibeji ọhun, ni wọn sọ wọn lorukọ, amọ mama ikoko ṣi wa ninu ara tutu, o n gba itọju lọwọ, ni wọn ba tẹ awọn Taye-Kẹyin ṣitosi rẹ lori bẹẹdi kekere ti wọn, ni ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ti Tafawa Balewa University Teaching Hospital.
Ko pẹ lẹyin eyi ni obinrin kan de, o mura gẹgẹ bi awọn nọọsi ṣe n mura gẹlẹ, o si ba mama ibeji sọrọ nibi to dubulẹ si pe oun fẹẹ gbe ọkan ninu awọn ibeji naa lọ si wọọdu keji, o lo nilo itọju, dokita lo ni koun gbe e wa, niya ọmọ ba ni ko buru o.
Laarin iṣẹju diẹ, obinrin ‘nọọsi aramanda’ yii ti poora bii iso, o si ti gbe ọmọ ọlọmọ lọ.
Iya ikoko naa ko tete fura, o ṣi n reti ki nọọsi da ọmọ oun pada, amọ nigba ti iṣẹju n di wakati, tawọn alejo n beere ejirẹ keji lọwọ ẹ, lo ba kesi nọọsi mi-in pe ki wọn ba oun pe nọọsi ẹlẹgbẹ wọn to waa gbe ọmọ oun lọ sọdọ dokita, ibẹ laṣiiri ti tu pe gbọmọgbọmọ lo dibọn bii nọọsi, o si ti gbọmọ lọ.
Kia ni wọn ti kan sileeṣẹ ọlọpaa, lawọn ọtẹlẹmuyẹ lati ileeṣẹ DSS ba bẹ sigboro, wọn bẹrẹ si i wa gbogbo awọn ile ti wọn fura pe obinrin to ji ọmọ naa le wa, lati ọọdẹ kan si ikeji ni wọn n lọ kaakiri, ṣugbọn wọn ko ri ẹni to jọ ọ, wọn o si ri ọmọ ọwọ naa.
Aṣe bi obinrin yii ti kuro lagbegbe ọsibitu naa, abule wọn, ti wọn n pe ni Dull, nijọba ibilẹ Tafawa Balewa, lo kọri si, ibẹ lo ti lọọ yayọ ọmọ fun wọn pe oun ti bimọ o, ki wọn ba oun yọ.
Ṣugbọn nigba ti ọkọ rẹ de sabule ọhun, wọn lọkunrin naa fariga pe oun o gba, o beere pe igba wo niyawo oun loyun, igba wo lo rọbi toun ko mọ, debi to fi waa di iya ikoko lọsan-an kan oru kan yii. Wọn lo paṣẹ fun iyawo rẹ ọhun pe ko yaa tete lọọ da ọmọ naa pada sibikibi to ba ti ri i, tori oun o le waa ma tọmọ toun o mọbi to ti wa.
Ẹnu ọrọ yii ni wọn wa ti wọn fi gbọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti n wa ẹni to ji ọmọ ikoko gbe kiri ilu.
Awọn ti wọn kẹẹfin obinrin to diya ọlọmọ lojiji yii ni wọn gbẹyin lọọ sọ fawọn ọlọpaa, eyi lo jẹ ki wọn tọpasẹ obinrin naa, ti wọn si i mu pẹlu ikoko ọwọ rẹ ni nnkan bii aago kan oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii.
.Lagọọ ọlọpaa, wọn beere bawo lọrọ ṣe jẹ, obinrin naa si jẹwọ pe loootọ loun ko bimọ, oun o tiẹ loyun aarọ dalẹ ri, niṣe loun lọọ ji ọmọ naa gbe lọsibitu. O ni ẹlẹya, eebu ati keeta tawọn ọrẹ oun atawọn mọlẹbi ọkọ oun n ṣe soun latari airọmọbi oun, to jẹ niṣe loun n da ẹkun sun pẹlu ibanujẹ, nigba toun o si lowo lọwọ toun iba fi lọọ gba ọmọ tọ, eyi lo fa a toun fi ṣe ohun toun ṣe naa.
Nigba ti wọn n fa Ibrahim le awọn obi rẹ lọwọ lọjọ naa, iya ọmọ naa ni o ya oun lẹnu bi obinrin ọhun ṣe ri ọmọ oun ji gbe lọ, tori nigba to waa ba oun, toun si ri aṣọ nọọsi lọrun ẹ, pẹlu bo ṣe n ṣaajo, o lo bi oun leere pe ewo ni Taye, ewo ni Kẹyinde ninu awọn ọmọ naa, oun si fi Taye han an, lo ba nawọ gbe e mọra, o lo da bii ọmọ naa ko ri ọyan mu daadaa, oun fẹẹ fi i han dokita, ki wọn le pese ohun tawọn ọmọde ti ko rọyan mu daadaa.
Ọga agba ọsibitu naa, Dokita Haruna Liman, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lakolo awọn ọlọpaa lobinrin yii ṣi wa, wọn si ṣi n ba iṣẹ iwadii wọn lọ.