Pasitọ Fẹmi ati Aafaa Kabiru ni mo maa n ta ẹya ara oku ti mo ba hu fun-Ismaila

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ismail Adewuyi, ọmọ ọdun mejidinlọgbọn, to ge ori nitẹẹku awọn Musulumi ti wa niluu Ẹdẹ, ti foju bale-ẹjọ Majisreeti ilu naa, adajọ si ti paṣẹ pe ki wọn fi wọn pamọ sakolo ọlọpaa.

Ismail lọwọ awọn ọdẹ (Nigeria Hunters and Forest SecurityServices) tẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lọwọ tẹ Ismail lẹyin to ge ori oku iya kan, to si tun ge apa oku mi-in pẹlu ifun rẹ.

Nigba ti wọn mu un de agọ ọlọpaa ẹka to n ṣewadi iwa ọdaran lo jẹwọ pe awọn meji lawọn ṣiṣẹ naa, ṣugbọn ẹni keji oun ti n jẹ KK ti sa lọ.

Bakan naa lo darukọ awọn afurasi meji mi-in; Pasitọ Fẹmi ati Aafa Kabiru, o ni awọn yẹn loun maa n ta awọn ẹya ara toun ba ni fun.

Lara awọn ẹsun ti Agbefọba, Sunday Adepọju, fi ko wọn wa si kootu ni igbimọ-pọ huwa buburu ati ṣiṣe oku baṣubaṣu, ṣugbọn ko lanfaani lati ka awọn ẹsun naa nitori adajọ Majisreeti naa, B. Adeboye, sọ pe kootu oun ko lagbara lati gbọ awọn ẹsun naa.

Adeboye ni ki agbẹjọro awọn ọlọpaa (OC Legal) mu iwe wa nilana ofin lati beere fun aṣẹ lati ko awọn afurasi naa lọ sọgba ẹwọn laarin ọjọ mẹrinla.

Ko too digba naa, o ni ki wọn ko awọn mẹtẹẹta pada si akolo ọlọpaa ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran titi tigbẹẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ ni kootu to lagbara lati gbọ ẹjọ wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alaga fun gbogbo Musulumi ilẹ Ẹdẹ, Alhaji Babatunde Ẹlẹsin, ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ niyi ti iru iṣẹlẹ bẹẹ yoo ṣẹlẹ nitẹẹku naa, ti ko si dun mọ awọn ninu rara.

O ni iṣẹ Ọlọrun ni bi ọwọ ṣe tẹ Ismail, ti aṣiri rẹ si tu faraye nitori gbogbo igbiyanju awọn ẹṣọ alaabo tawọn n gba sibẹ lo n ja si pabo latẹyin wa pẹlu bo ṣe jẹ pe ṣe lawọn oniṣẹ ibi naa maa n ṣọ asiko ti awọn alaabo maa n gba iṣẹ lọwọ ara wọn, ti wọn fi maa n raaye wọnu itẹẹku naa.

Alhaji Ẹlẹṣin sọ siwaju pe idajọ ododo lawọn fẹ lori ọrọ naa, o si fi gbogbo ilu lọkan balẹ pe aabo to daju wa fun awọn oku ti wọn ba gbe wa sitẹ naa, nitori eto aabo ibẹ tun ti lagbara si i.

Leave a Reply