Ọṣinbajo ṣi ile ẹgbẹ awọn gomina l’Abuja

Monisọla Saka

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022 yii, ni Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ṣi ile ipade awọn gomina ilẹ wa niluu Abuja.

Ọṣinbajo to tukọ eto ṣiṣi ile nla ọhun lọ sibẹ lati ṣoju Aarẹ Muhammadu Buhari.

Lori ayelujara Tuita (Twitter) rẹ ni Ọṣinbajo ti sọ eleyii di mimọ. Bẹẹ lo gbe awọn fọto ti wọn ya lasiko ti eto naa n lọ lọwọ sibẹ pẹlu.

O kọ ọ sibẹ pe, “Pẹlu inu didun ni mo fi ṣi ile ipade tuntun ẹgbẹ awọn gomina ilẹ yii lorukọ Aarẹ Muhammadu Buhari”.

Aarẹ ẹgbẹ awọn gomina lapapọ, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, atawọn gomina ilẹ Naijiria ti wọn wa nipo lọwọlọwọ titi kan gomina ana nipinlẹ Rivers, Rotimi Amaechi, gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ toun naa ti figba kan jẹ alaga awọn gomina, Dokita Bukọla Saraki, gomina ipinlẹ Edo tẹlẹ, Dokita Lucky Igbinedion atawọn mi-in bẹẹ ni wọn peju sibi eto naa. ni wọn peju pesẹ sibẹ.

Leave a Reply