Monisọla Saka
Lagbegbe tawọn eeyan nla, awọn to rowo ṣe fuja, n gbe ni Victoria Garden City, Lekki, nipinlẹ Eko, ni ajọ to n gbogun ti oogun oloro ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, NDLEA mu ọkunrin ọmọ jayejaye olowo Eko kan, Ugochukwu Nsofor Chukwukadibia, ẹni ọdun mejilelaaadọta(52), to jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ihiala, nipinlẹ Anambra, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. Oogun oloro ti wọn n pe ni Tramadol saṣẹẹti to le ni miliọnu mẹtala ni wọn ka mọ ile rẹ.
Gẹgẹ bi Fẹmi Babafẹmi to jẹ Agbẹnusọ ajọ ọhun ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi lede, o ni ọkan ninu awọn agba ọjẹ nidii iṣẹ to lodi sofin yii lo ni ile naa. O ni o pe pẹ tawọn ti n fimu finlẹ nipa ẹ kawọn too waa fi panpẹ ofin gbe e nile ibi to n ko ọja si ọhun laaarọ kutukutu ọjọ Aje, to si ti wa latimọle bayii.
Oogun oloro Tramadol ti wọn ri ninu ile ọhun to jẹ ṣaṣẹẹti lọna miliọnu mẹtala (13 million), ni wọn sọ pe yoo to ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu owo Naira. Ọgbẹni Ugochukwu yii naa tun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ to n ta mọto ti wọn n pe ni Automation Motors Limited, l’Ekoo. Ohun to daju ni pe, bojuboju lo n fi iṣẹ mọto yii ṣe, kaye ma baa fura si ẹru ofin to wa lakata ẹ.
O ni, “A tun ri ibuba ati ile ti wọn n ko awọn elegboogi oloro pamọ si, bii ile to wa lagbegbe VGC, Lekki, niluu Eko, ti wọn ṣe ringindin, to dun un wo. Ko si ẹda Ọlọrun kankan to n gbe ninu ile daradra naa, oogun oloro Tramadol, oriṣii oogun lile kan tijọba ti fofin de nitori iṣẹ buruku to n ṣe lara, ni ọkunrin olowo bilọnia to jẹ ogbontarigi oniṣowo oogun oloro ọhun ko pamọ sinu ẹ, o si ti wa lakolo wa bayii”.