Yusuf yinbọn pa aburo rẹ nibi ti wọn ti n dan oogun ayẹta wo ni Kwara

 

Ibrahim Alagunmu

Ọrọ naa ko jọ oju lasan loju awọn eeyan, gbogbo awọn ti wọn n gbọ ọ ni wọn n sọ pe eedi ni ọrọ ọhun pẹlu bi ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Abubakar Abubakar ṣe yinbọn pa aburo rẹ ti ko ju ọmọ ọdun mejila lọ, Yusuf Abubakar ni Kwara.

ALAROYE gbọ pe ọdẹ ni baba awọn ọmọ mejeeji to jẹ pe iya kan ati baba kan naa lo bi wọn, ti wọn n gbe ni ilu kan ti wọn n pe ni Dutse Gogo, ti ko jinna rara si Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara.

Ko ṣeni to le sọ ibi ti awọn ọmọde meji naa ti lọọ ṣe oogun ayẹta. Oogun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe naa ni wọn fẹẹ dan wo lara wọn ti ọrọ fi yiwọ, to si pada ja si iku fun Yusuf, ọmọọdun mejila.

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ ALAROYE lọwọ latọdọ Alukoro ọlọpaa ni Kwara, SP Okesanmi Ajayi, ṣe sọ, o ni niṣe lawọn ọmọ mejeeji ti wọn jẹ omọ iya kan naa yii fẹẹ dan oogun ayẹta kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣe wo. Yusuf ti fi oogun naa sara, n ni ẹgbọn rẹ, Abubakar, ba lọọ gbe ibọn baba wọn to jẹ ọdẹ ninu ile, lo ba kọju rẹ si aburo rẹ, o yin in pẹlu igbagbọ pe oogun ayẹta to wa lara rẹ ko ni i jẹ ki ibọn naa wọle si i lara.

Ṣugbọn nigba ti awọn ọmọde meji yii yoo fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, niṣe ni Yusuf digbo lulẹ, to si ku patapata, ọrun ni ibọn naa ti ba a. Bi ẹgbọn ṣe ri i pe oun ti pa aburo oun lo ba kan lugbẹ.

Alukoro ọlọpaa Kwara sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ naa gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Paul Odama, ṣe paṣẹ.

Okesanmi waa rọ awọn obi lati maa kiyesi awọn ọmọ wọn lati dena iru ajalu bayii.

Leave a Reply