Igbimọ Aṣee-fọkan-tan (BOT) ẹgbẹ PDP fẹẹ ṣepade pẹlu Wike

Ni isapa lati wa gbogbo ọna ti alaafaia yoo fi jọba, ti ede aiyede to n lọ laarin awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo fi dopin, igbimọ Aṣee-fọkan-tan ẹgbẹ naa, iyẹn Board of Trustee (BOT), ti tun gbera lọ si ilu Porthacourt, nipinlẹ Rivers, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla yii,  lati ṣepade alaafia pẹlu Gomina ipinlẹ naa, Nyesom Wike, lori fa-a-ka-ja-a to ti n lọ laarin oun atawọn gomina pẹlu agbaagba ẹgbẹ kan lori ọrọ alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu, ti wọn fẹ ki wọn yọ nipo.

Alaga igbimọ BOT yii, Adolphus Wabara, lo ṣiwaju awọn ọmọ igbimọ rẹ lọ si ipinlẹ Rivers lati lọọ ri Wike. Ọsan ọjọ Iṣẹgun ni ipade naa yoo waye gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i sọ ibi ti yoo ti waye ni pato.

Tẹ o ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta ti ede aiyede ti n ṣẹlẹ laarin gomina Rivers atawọn agbaagba ẹgbẹ PDP, pẹlu oludije ẹgbẹ wọn funpo aarẹ, Atiku Abubakar. Ohun to fa wahala yii ko sẹyin bi Wike ṣe faake kọri pe dandan ni ki Ayu fipo silẹ gẹgẹ bii alaga, gẹgẹ bi ileri to ṣe ki eto idibo abẹle wọn too waye pe to ba jẹ pe Oke-Ọya ni wọn ti fa oludije dupo aarẹ kalẹ, oun maa kọwe fipo alaga silẹ niwọn igba to jẹ pe Oke-Ọya loun naa ti wa, nitori ẹni kan ki i jẹ ki ilẹ fẹ. Adehun yii ni alalga naa ko fẹẹ mu ṣẹ mọ, niṣe lo yari pe ko sohun to jọ ọ. Ṣugbọn Wike atawọn kan ninu ẹgbẹ naa ti yari pe afi ti ọkunrin yii ba fipo silẹ nikan ni awọn jọ le jokoo sọrọ lori pe awọn yoo ṣatilẹyin fun Atiku lasiko ibo ọdun to n bọ.

Leave a Reply