Ifa o fọre fun ASUU, ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ni ki wọn pada si yara ikawe kia

Faith Adebọla

Ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lorileede wa, Academic Staff Union of Universities (ASUU), pe ta ko aṣẹ ile-ẹjọ apapọ to n gbọ ẹsun laarin ileeṣẹ kan sikeji, National Industrial Court, INC, pe ki wọn wọgi le iyanṣẹlodi wọn, ki wọn pada si yara ikawe, ifa kọ ko fọre fun ASUU lori ipẹjọ naa o, tori ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti wọn lọ ti paṣẹ pe afi ki wọn kọkọ pada sẹnu iṣẹ lẹyẹ-o-sọka na, nigba naa ni atotonu wọn to le wọ’ti.

Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta kan, eyi ti Adajọ Hamman Barka lewaju fun, lo gbe aṣẹ naa kalẹ lowurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ta a wa yii, nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to fikalẹ siluu Abuja.

Ṣe ṣaaju ni ile-ẹjọ INC tijọba apapọ wọ ASUU lọ ti paṣẹ lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, pe oun fara mọ ipinnu ijọba apapọ pe ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ọhun pada sẹnu iṣẹ wọn laisọsẹ, ṣugbọn aṣẹ yii ko tẹ ASUU lọrun, eyi ni lo mu ki wọn pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an kan naa.

Lara ẹbẹ ti wọn fi siwaju ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, nipasẹ lọọya wọn, Amofin agba Fẹmi Falana atawọn ẹmẹwa ẹ ni pe kile-ẹjọ wọgi le aṣẹ lati pada si kilaasi ọhun.

Awọn olukọ naa ni inu didun ni i mori ya, olukọ ti inu ẹ ko ba dun ko le kọ akẹkọọ lọna to ja geere, wọn ni ko tẹ awọn lọrun bile-ẹjọ ṣe ni kawọn maa ba iṣẹ lọ na, ki wọn too yanju awọn ibeere ati lọgbọ-lọgbọ to wa laarin awọn atijọba apapọ, eyi to ṣokunfa iyanṣẹlodi fọpawọn wọn ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ni awọn fọwọ si awọn ibeere ASUU, awọn si gba lati yiiri ẹ wo ki wọn le gbe idajọ kalẹ lori ẹ, wọn ni ohun to yẹ ni ki ASUU kọkọ pada si yara ikawe na, wọn lo bẹtọọ mu ki wọn kọkọ tẹle aṣẹ tile-ẹjọ INC pa na, tori ẹ, wọn paṣẹ fun wọn lati wọgi le iyanṣẹlodi naa lẹyẹ-o-sọka, bẹrẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2022.

Ile-ẹjọ naa ni bi ASUU ko ba pada ṣẹnu iṣẹ loju-ẹsẹ, ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti wọn pe ko le lẹsẹ nilẹ, tori gẹgẹ bii ilana to rọ mọ ipẹjọ kọ-tẹ-mi-lọrun ṣe wi, ASUU gbọdọ kọkọ fẹri han pe awọn ti tẹle aṣẹ ti wọn n pẹjọ ko tẹ mi lọrun le lori ọhun naa. Lede mi-in, wọn ni wọn o le wa lẹnu iyanṣẹlodi, ki wọn tun maa pẹjọ ta ko jijawọ ninu iyanṣẹlodi, ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ ni ipẹjọ wọn le bofin mu.

Ko ti i daju boya ASUU maa tẹle aṣẹ yii abi wọn maa gbe igbesẹ mi-in lọ sile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa.

Bi ASUU ba tẹle aṣẹ tile-ẹjọ pa ọhun, ayọ abara-tintin leyi yoo jẹ fawọn akẹkọọ fasiti atawọn obi wọn ti wọn ti n reti ki opin de ba iyanṣẹlodi to ti ṣakoba fun eto ẹkọ lati oṣu meje sẹyin ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2022 yii, ni ASUU ti gun le iyanṣẹlodi latari awọn ibeere kan ati awuyewuye lori ilana tijọba yoo fi maa sanwo-oṣu fun wọn, eyi ti wọn o ti i fori ikooko ṣọọdun le lori latigba naa di ba a ṣe n sọ yii.

Leave a Reply