Gomina AbdulRazaq fun iyawo atawọn ọmọ Aafa Aboto ni miliọnu mẹwaa Naira

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ẹsẹ ko gbero l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nibi adura ọjọ kẹjọ Aafa Aboto to ku niluu Aboto, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara.

Nibi eto naa ni gomina ti juwe iku Aafaa Aboto gẹgẹ bii ohun to ba ni lọkan jẹ, to si jẹ adanu nla fun ilu Aboto, ajọ Adabiya ati gbogbo Musulumi lapapọ.

O fun mọlẹbi oloogbe ni miliọnu mẹwaa Naira, o si fun ileekewu aafaa yii ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500,000). Bakan na ni Saliu Mustapha fun mọlẹbi naa ni ile ti wọn yoo maa gbe.

Lara awọn to peju sibi eto adura naa ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, Alifa Adabiya, Onimọ-ẹrọ Musa Kamalideen, Oludasilẹ Fasiti Al-Ikmah, Ọladimeji Igbaja, Mufty tilu Ilọrin, Sulaiman Faruq Onikijipa, aṣoju Ẹmia ilu Ilọrin, Daudu Afọn, Sannu Sheu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply