Bawọn eleyii ṣe fibọn gba ọkada tan l’Akute ni wọn mu wọn!

Gbenga Amos, Ogun

Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa yii, lawọn gende mẹrin kan, Kacha, Yusuf Mohammmed ati Muhammed Adamu ko sakolo awọn ẹṣọ alaabo Social Orientation and Safety Corps, ti wọn n pe ni So-Safe, lagbegbe Akute, lẹyin ti wọn ṣẹṣẹ fibọn gba ọkada ọlọkada kan tan. Nigba ti wọn tun lugọ lati gba omi-in lọwọ tẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe ẹni kẹrin wọn sa lọ tefetefe.

Oludari eto iroyin So-Safe nipinlẹ Ogun, Moruf Yusuf, ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde yii, sọ pe o ti pẹ tawọn adigunjale yii ti n han awọn eeyan agbegbe Iṣẹri si Akute leemọ, paapaa awọn to n gun ọkada nibẹ, bi wọn ṣe n ja wọn lole owo ati dukia, ni wọn tun n ji ọkada gbe sa lọ, ti wọn ko si ri wọn mu.

O ni olobo kan lo ta awọn ẹṣọ alaabo naa lọsan-an ọjọ Aiku ti wọn tun ṣiṣẹẹbi wọn, ẹnikan lo tẹ Eria Kọmanda So-Safe, ẹka ti Iṣẹri Oluwarotimi Ige, laago, lati fi iṣẹlẹ naa to o leti, ni wọn ba bẹrẹ si i tọpasẹ awọn gbewiri ẹda yii.

Lẹyin ti wọn ti lọọ tọju ọkada ti wọn ji gbe sibi kan tan, niṣe lawọn afurasi yii tun dọgbọn ṣe bii ero to fẹẹ gun ọkada, mẹta ni wọn, ọtọ nibi ti ẹkẹrin wọn fara pamọ si ni tiẹ, wọn duro sabẹ igi kan nitosi gareeji Tipper, l’Onibudo, Akute, nijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun, wọn wọn n wo ọkada mi-in ti wọn fẹẹ ji gbe, ibẹ lawọn ẹṣọ So-Safe ka wọn mọ.

Nigba tọwọ ba wọn, ti wọn yẹ ara wọn wo, ibọn agbelẹrọ pompo meji ni wọn ba, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹta, irin gbọọrọ kan ti wọn fi n ṣe ẹni to ba ba wọn ṣagidi ni ṣuta, ati ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ ni wọn n ko kiri.

Wọn lawọn afurasi naa ti jẹwọ p’awọn ni firi-nidii-ọkẹ alọ-kolohun-kigbe agbegbe naa. Kacha ni Ojule ogun, Opopona Omega, niluu Onibudo, loun n gbe, ilu Onibudo naa ni Yusuf n gbe, Adamu ni ile tiẹ yatọ, abẹ biriiji kan ni Akute loun fi ṣe ile.

Ṣa, wọn ti ṣeto lati fa awọn afurasi yii le ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwọ, ki wọn le tubọ ṣewadii to lọọrin nipa wọn, ki wọn si foju wọn bale-ẹjọ, nibi ti wọn yoo ti fimu kata ofin.

Leave a Reply