Oluṣẹyẹ Iyiade
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Dokita Olusẹgun Mimiko, ti ṣẹ kanlẹ lori iroyin kan ti wọn n gbe kiri laipẹ yii pe o ti kẹyin si ọrẹ rẹ, iyẹn Nyesome Wike, to n tukọ ipinlẹ Rivers lọwọlọwọ pẹlu bo ṣe lọọ darapọ mọ ikọ ipolongo oludije sipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn aṣaaju ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo darukọ awọn eeyan ti iye wọn to bii oji-le-n’irinwo-le-ẹyọkan (441) gẹgẹ bii awọn ọmọ igbimọ ti yoo polongo ibo fun Atiku ṣaaju eto idibo gbogbogboo to fẹẹ waye lọdun to n bọ.
Mimiko ni wọn ni yoo jẹ adari gbogbogboo fun ikọ olupolongo ibo ọhun, Ambasadọ Roland Ọmọwa ni yoo si jẹ alaga patapata, nigba ti Amofin agba Eyitayọ Jẹgẹdẹ jẹ igbakeji alaga.
Ni kete ti wọn ti fi awọn orukọ yii sita lawọn ọmọ ẹgbẹ kan ti fa ibinu yọ, ti wọn si n fi aidunnu wọn han si orukọ Mimiko ti wọn fi sinu awọn ọmọ igbimọ naa, niwọn igba ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ mọ pe ko si ni iha awọn to fara mọ bi Atiku ko ṣe yọ Ayu gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ wọn.
Ori eyi ni wọn wa ti wọn ko ti i ri i yanju ti gomina ana ọhun fi da wọn lohun pe oun gan-an ko ṣetan lati kọ ẹyin si Wike lati waa ṣiṣẹ fuj jijawe olubori Atiku ninu ẹgbẹ PDP.
Mimiko ninu atẹjade to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, John Paul Akinduro, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ni ahesọ ati ayederu patapata ni iroyin naa jẹ nitori pe digbi loun ṣi wa lẹyin Wike, bẹẹ ni ko si ki ẹnikẹni fi orukọ oun sinu igbimọ kan lai kọkọ bun oun gbọ nipa rẹ.
O ni oun gbagbọ pe awọn ọbayejẹ kan ni wọn ṣe agbatẹru iroyin ofege naa lati ba orukọ rere oun jẹ pẹlu bi wọn ṣe ni oun ti kẹyin si Makinde, Wike atawọn gomina yooku ti awọn jọ n ja fun pipin nnkan dọgbadọgba ninu ẹgbẹ PDP.
Mimiko ni oun ko ṣetan ati yi ipinnu oun pada rara, nitori oun ni igbagbọ pe aiṣegbe, pipin ipo lori-o-jori ati idajọ ododo nikan ni ẹgbẹ PDP fi le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ yii.