Wọn ti mu awọn ole to lọọ ji ọpọlọpọ aso nileetaja kan l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igan aṣọ bii ọgọsan-an lawọn ole meje kan tọwọ ọlọpaa ti tẹ bayii ji gbe l’Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ. Orukọ awọn to ṣiṣẹ buruku naa ni Ajao Ismail, ẹni ọdun mejilelogun (22);  Raheem Isiaka, ẹni ọdun marundilogoji (35); Ọpalade Mayọwa, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32); Bayọ Ọmọniyi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31);  Ọlayiwọla Hammed, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), Abass Soliu, ẹni ọdun mọkanlelọgbọ̀n (31), ati baba ẹni aadọta (50) ọdun kan to n jẹ Moses Alabi.

Gẹgẹ bi SP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, awọn agbofinro to n paara oju titi ọna Ogbomọṣọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, ni wọn mu awọn mejeeje lasiko ti wọn n ko ẹru aṣọ ti owo ẹ to miliọnu mẹẹẹdọgbọn (25m) ọhun lọ.

O ni ṣiṣọ ti awọn ọlọpaa n ṣọ oju titi ọhun ko ṣẹyin bi wọn ṣe gbọ ṣaaju pe awọn eeyan kan n gbe ọja ti wọn ji ko nileetaja oniṣowo aṣọ kan bọ ni ọna Ogbọmọṣọ.

Awọn mejeeje pẹlu ọkọ bọọsi kan ti nọmba rẹ jẹ AKD 360 YF ati KWL 125 Cfni wọn mu. Gbogbo wọn ni wọn jọ wa lahaamọ awọn ọlọpaa n’Ibadan bayii.

Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ yii, CP Williams Adebọwale, sọ pe laipẹ lawọn afurasi ole mejeeje yii yoo foju bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply