Iya agbalagba kan, Abilekọ Cecilia Idowu, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisireeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, l’Akurẹ, lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o ju oku ayalegbe rẹ, Stephen Haruna, sinu kanga lẹyin to pa a tan niluu Oke-Agbe Akoko.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye laarin aago mẹwaa alẹ si mẹrin idaji, ninu ile rẹ to wa laduugbo Oke-Igbala, lagbegbe Oge, l’Oke-Agbe.
Ẹsun ipaniyan ati gbigbimọ–pọ huwa to lodi sofin ni wọn fi kan iya ẹni ọdun marundinlọgọta ọhun lọjọ akọkọ to foju bale-ẹjọ.
Agbefọba, Simon Wada, sọ ninu alaye rẹ pe olujẹjọ ọhun ati ayalegbe rẹ nikan ni wọn jọ wa nile lọjọ iṣẹlẹ naa. O ni iwadii fi idi rẹ mulẹ pe epo pupa to fun ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn naa mu laarin oru lo ṣokunfa iku rẹ.
Lẹyin eyi lo ni obinrin naa lọọ bẹ awọn eeyan kan lọwẹ, ti wọn si jọ ju oku Haruna sinu kanga kan to wa ninu ọgba ile rẹ.
Wada ni olujẹjọ funra rẹ jẹwọ nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ni tesan pe oun ri Haruna nigba to pada wọle ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ iṣẹlẹ ọhun, bakan naa lo ni awọn tun ṣawari igbá kan ti epo pupa kun inu rẹ fọfọ nibi ti afurasi ọhun n gbe.
O ni idi ti wọn fi pa ọkunrin naa si ṣokunkun si awọn ọlọpaa, bẹẹ ni awọn ko ti i le fidii ọna to fi mu epo pupa to mu ati ohun to ṣokunfa bi wọn ṣe ju oku rẹ sinu kanga mulẹ.
Abajade ayẹwo tawọn dokita ṣe lori iku to pa Haruna ni wọn lo fidi rẹ mulẹ pe amuju epo pupa to mu lo ṣeku pa a
Ẹsun mejeeji ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun ni wọn lo ta ko abala okoo-le-lẹẹẹdẹgbẹta-din mẹrin ((516) ati okoo-le-lọọọdunrun-din-mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2022.
Agbefọba bẹbẹ pe ki wọn fi olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta titi di gba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Amofin A. Adedire to jẹ agbẹjọro olujẹjọ ta ko aba yii ninu ẹbẹ tirẹ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ lọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, Adajọ Kootu ọhun, Onidaajọ Musa Al-Yunnus, kọ lati gba ẹ̀bẹ̀ agbefọba wọle.
Onidaajọ Al-Yunnus ni ko si ẹri to to lati fi mama agbalagba naa pamọ sọgba ẹwọn gẹgẹ bii ibeere rẹ, bẹẹ lo ni oun ko ṣetan lati tu afurasi naa silẹ ko maa lọ, nitori pe ẹsun ti wọn fi kan an lagbara pupọ labẹ ofin.
O waa faaye beeli silẹ fun un pẹlu Miliọnu marun-un Naira ati oniduuro meji ni iye owo kan naa.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.