Monisọla Saka
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti rọ ile-ẹjọ lati wọgi le iyansipo awọn ọmọ igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ oṣelu APC, eyi ti Abdullahi Adamu n dari gẹgẹ bii alaga wọn nipo naa, nitori ọna ti ko lẹsẹ nilẹ, ti ko tọna, ti ko si bofin mu ni wọn fi yan awọn oloye ẹgbẹ ọhun ati awọn aṣoju wọn fun eto idibo ọdun to n bọ.
Ninu iwe ipẹjọ ti agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Ayọ Kamladeen Ajibade, gbe siwaju kootu lorukọ ẹgbẹ PDP lo ti n rọ ile-ẹjọ pe ko wọgi le gbogbo awọn oludije to fẹẹ dupo kan tabi omi-in ninu idibo ọdun to n bọ lorukọ ẹgbẹ APC nitori igbimọ to yan wọn ti ṣe lodi si ofin ilẹ wa ti ọdun 1999, ati ofin to rọ mọ eto idibo ti wọn n pe ni Electoral Act, ti ọdun 2022 yii.
Wọn gbe ẹjọ ti wọn pe yii lori idajọ kan to ti waye ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, leyii ti adajọ ti dajọ pe gbogbo igbesẹ ti Gomina ipinlẹ Yobe to duro bii adele alaga ẹgbẹ naa gbe gẹgẹ bii alaga igbimọ pataki to yan awọn to ri si ipade apapọ egbẹ naa lodi sofin.
Lara awọn ti ẹgbẹ PDP n bẹ kootu pe ko wogi le iyansipo wọn lati dupo lọdun to n bọ ni oludije sipo aarẹ ẹgbẹ APC ninu ibo ọdun to n bọ, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, gbogbo awọn oludije sipo gomina ati igbakeji wọn, awọn oludije sipo aṣofin agba ati awọn aṣoju-ṣofin.
Adajọ agba fun ile-ẹjọ giga ilẹ wa, Onidaajọ John Tsoho, ti waa gbe ẹjọ naa ti nọmba rẹ jẹ FH/ABJ/CS/1864/2022, fun Onidaajọ Inyang Edem Ekwo lati gbọ.
Bẹẹ ni adajọ yii ti fi igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla yii. O waa paṣẹ pe ki wọn fi iwe ipẹjọ ranṣẹ si gbogbo awọn mẹtẹẹtalelaaadọta ti ẹgbẹ PDP darukọ ninu iwe ipẹjọ wọn.