Oluwoo ranṣẹ ibanikẹdun si idile Adeleke lori iku ọmọ Davido

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ranṣẹ ibanikẹdun si idile Adeleke lori iku ọmọ David Adeleke, Ifeanyi.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin kabiesi, Alli Ibraheem, fi sita lorukọ ọba naa, Oluwoo ṣapejuwe iroyin iku naa gẹgẹ bii agbọ-sọgba-nu.

O ni, “Pipadanu ọmọ to ṣe iyebiye jẹ ẹdun ọkan nla, ṣugbọn eeyan gbọdọ gba fun Ọlọrun.

“Mo ba Davido, Dokita Deji Adeleke, gomina tuntun l’Ọṣun, Senetọ Ademọla Adeleke, ati gbogbo idile Adeleke niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, kẹdun lori iṣẹlẹ naa. Mimu ọkan ro lasiko yii jẹ ọkan lara iwa Ọlọrun.

“Ki Ọlọrun tubọ maa tọ idile naa, ko si daabo bo wọn”.

Leave a Reply