Oyetọla/Adeleke: Ile-ẹjọ ti gba ẹri ibo ti wọn di ju lawọn ijọba ibilẹ meje

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, ti gba awọn akọsilẹ ẹsun àdìjù ibo ti Gomina Gboyega Oyetọla gbe siwaju ẹ.

Ijọba ibilẹ mẹwaa ni Oyetọla ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC, gbe siwaju ile-ẹjọ pe adiju ibo ti waye, to si sọ pe ti wọn ba yọ awọn ibo naa kuro gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin idibo orileede yii, o di dandan ki oun gba kinni naa pada lọwọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Ninu ijokoo kootu lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ yii, lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan laarin awọn agbẹjọro fun olupẹjọ, iyẹn, Gomina Oyetọla ati ẹgbẹ APC, pẹlu ti awọn olujẹjọ, iyẹn Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ẹgbẹ PDP ati ajọ INEC, awọn igbimọ onidaajọ naa sọ pe awọn yoo gba awọn akọsilẹ to duro fun ẹri naa wọle.

Lọjọ naa, wọn gba akọsilẹ esi idibo (Forms EC8As) nijọba ibilẹ mẹta; ijọba ibilẹ Oṣogbo, ijọba ibilẹ Ariwa Ẹdẹ ati ijọba ibilẹ Guusu Ẹdẹ.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, awọn igbimọ naa, labẹ alaga wọn, Onidaajọ Tertsea Kume, gba awọn akọsilẹ lati ijọba ibilẹ mẹrin miiran, iyẹn ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, Ejigbo, Iwọ Oorun Ileṣa ati Irẹpọdun.

Agbẹjọro to ṣoju fun Oyetọla, Lateef Fagbemi (SAN), sọ pe ẹtọ olupẹjọ ni labẹ ofin lati gbe ẹdun ọkan rẹ lọ si kootu pẹlu gbogbo ẹri to ba ni.

Bo tilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro fun awọn olujẹjọ; Barisita Niyi Owolade, Nathaniel Ọkẹ (SAN), ati Ọlakunle Faokunla, ta ko gbigbe awọn akọsilẹ naa kalẹ, sibẹ wọn ni awọn yoo fi itako awọn han ninu akọsilẹ awọn (Final written address).

Lẹyin eyi ni wọn sun ijokoo si Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lati gba akọsilẹ awọn ijọba ibilẹ mẹta to ku wọle.

Leave a Reply