Dubai nile Atiku, yoo tun pada sibẹ tawọn ọmọ Naijiria ba fibo ja a bọ lọdun to n bọ- Oshiomhole

Monisọla Saka

Igbakeji adari igbimọ eleto ipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole, ti sọ pe oun ni igboya ati ifọkanbalẹ pe awọn eeyan ilẹ yii maa tun ja oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar, kulẹ lasiko ibo aarẹ ọdun to n bọ.

Oshiomhole to jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Edo, lo n yan ọrọ kan ti wọn sọ ta ko ẹni ti yoo ṣe igbakeji aarẹ ninu ẹgbẹ wọn, Kashim Shettima, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lasiko to n sọrọ lori eto kan nileeṣẹ Tẹlifiṣan Arise TV, o lo da oun loju pe Atiku yoo tun dero Dubai pada lẹyin tawọn ba dibo tan lọdun 2023, tori ko ni i wọle.

O ni ta a ba tibi itan wo o, lati ọdun ti Atiku ti n gbegba ibo aarẹ lawọn ọmọ Naijiria ti n dojuti i, ti wọn o dibo fun un, to ba si ti di pe o ja lulẹ bayii ni yoo fori le Dubai rẹ. Oshiomhole waa sọ pe o da oun loju pe Atiku yoo tun mu ọna Dubai pọn ni kete ti ibo ba ti pari lọdun 2023, o loun gba a laduura kawọn ijọba Dubai ti gbegi le ofin to ni kawọn ọmọ Naijiria ma wa siluu awọn, ki adiẹ Atiku le rọna debi ẹyin ẹ pada.

O ni, “Ta a ba wo bi Atiku ṣe maa n ṣe latẹyin wa, to jẹ pe ti ko ba ti wọle ibo bayii, Dubai lo maa gba lọ. O ti to bii igba mẹta si mẹrin tawọn ọmọ Naijiria ti ja a kulẹ bayii, koda bo ṣe jẹ pe oun ati Obi ni wọn jọ lẹ pọ lasiko ti wọn gbegba ibo lọdun 2019, iyẹn o tori bẹẹ ni ko wọle. Nigba ti gbogbo ẹ maa tiẹ kuku waa dojuru patapata, Atiku o lẹsẹ nilẹ bii ti ọdun 2019 yẹn nisinyii.

O da wa loju gbangba gbangba pe, awọn eeyan wa yii kan naa ti wọn ti n fibo wọn le e pada sile lati ọdun yii wa ko tun ni i fibo gbe e wọle lọtẹ yii. Nitori bo si ṣe jẹ pe o ti wa ninu itan pe ti ko ba ti rọwọ mu ninu ibo bayii, o maa n ko lọ siluu Dubai titi digba tibo mi-in ba n bọ ni, o daju pe bẹẹ ni yoo tun ri lọdun to n bọ tori iṣe rẹ niyẹn. O da bii pe ọkan ẹ balẹ lọhun-un yẹn, ki ori ẹ ba a ṣe e, ki ofin ti wọn fi de awọn ọmọ Naijiria niluu yẹn ma kan an, ko le tete ribi pada sibi to rọ ọ lọrun”.

Bayii ni Oshiomhole dọgbọn ta si Atiku, o lo da oun loju pe ẹgbẹ awọn lo maa wọle lọdun to n bọ, tawọn yoo si fibo le Atiku pada sibi to ti n bọ nilẹ Dubai lọhun-un.

Leave a Reply