Awọn agbebọn lati ilẹ okeere ti gbakoso awọn ibi kan nilẹ Yoruba- Akintoye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu iroyin to lu sita bayii, pe awọn agbebọn to ti ilẹ okeere wa si Naijiria ti gbakoso awọn ibi kan nilẹ Yoruba, afi ki awọn ijọba ati gbogbo ọmọ Yoruba tete mura lelẹ.

Aṣaaju ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye, lo ke gbajare yii sita ninu ipade ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua to waye niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

A o ṣakiesi pe o ṣe diẹ ti awọn agbebọn ti n ṣoro lapa Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, to jẹ pe bi wọn ṣe n paayan ni wọn n ji awọn eeyan gbe.

Eyi ti gbogbo aye n sọ nipa ẹ lọwọlọwọ bayii leyi to waye loju ọna Eko s’Ibadan, nibi tawọn agbebọn ọhun ti ji awọn arinrin-ajo mẹfa gbe lẹyin ti wọn yinbọn paayan bii mẹrin, ti wọn si ṣe ọkẹ aimọye ẹni leṣẹ

Ọjọgbọn Akintoye Woye pe ilana ti a n gba ṣejọba Naijiria lo faaye gba ipenija eto aabo to wa nilẹ yii, ti ko si faaye silẹ fun eto lati dena tabi fopin si iṣoro naa.

O ni ọna abayọ kan ṣoṣo sọrọ wahala eto aabo yii ko ju ki ilẹ Yoruba da duro laaye ara wọn lọ.

O waa fi awọn ọmọ Kaaarọ-o-o-jiire lọkan, o ni nigba ti yoo ba fi di inu oṣu Kejila, ọdun 2022, ta a wa yii, eto gbogbo yoo ti pari lori idasilẹ Ilẹ Olominira Oodua, ti iran Yoruba yoo le maa mojuto eto aabo ilẹ wọn bi wọn ba ṣe fẹ.

Leave a Reply