Ọlawale Ajao, Ibadan
Ṣe idajọ Ọlọrun ni ka pe eyi ni abi afọwọfa? Eyi o wu ko jẹ, iroyin gbigbona to ṣẹlẹ n’Ibadan, lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ni tọkunrin kan to j’Ọlọrun ni pe nibi to ti n ba patako ipolongo ibo oloṣelu kan jẹ.
Ọkunrin ta o ti i mọ orukọ ẹ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii ni ina gbe, to si gan pa mọ’bẹ lasiko to n gbiyanju lati ba patako ipolongo ibo Oloye Bayọ Adelabu ti i ṣe oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party jẹ laduugbo Challenge, n’Ibadan.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe bi ọkunrin baṣejẹ yii ṣe fẹẹ gun ori opo ipolongo ibo giga naa ni wọn ti kilọ fun un lati ma ṣe ba a jẹ, ṣugbọn to kọ ti ko gbọ.
O ni “Bo ṣe gun opo yẹn doke tan, lẹẹkan naa la kan ri i to n ja pitipiti. A mọ pe o ti ṣeeṣi fara kan waya ina ni, ina si ti gbe e, ṣugbọn ko sẹni to le sun mọ ọn titi to fi gbẹmi-in mi’’.
Ọpọ ẹgbẹ oṣelu lo ti fi aidunnu wọn han nipa bi awọn janduku ṣe n ba nnkan ipolongo ibo wọn jẹ.
Lara awọn to ti sọrọ soke bẹẹ fawọn oniroyin laipẹ yii ni Oloye Bayọ Adelabu, ẹni to n dupo gomina ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu Accord; Sẹnetọ Teslin Fọlarin to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ati Oloye Olukayọde Popoọla to n dupo naa lorukọ ẹgbẹ oṣelu NNPP.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Oloye Bayọ Adelabu sọ pe “wọn ti fi iṣẹlẹ yẹn to wa leti. Awọn kan sọ pe ẹni yẹn n ri bii bọọdu yẹn ni, awọn kan sọ pe o n ba a jẹ ni’’.
Adelabu, ẹni to sọrọ ọhun nipasẹ Ọgbẹni Bọlaji Tunji, ti i ṣe oludari eto iroyin rẹ, sọ pe “ṣugbọn eyi o wu ko jẹ nibẹ, ibanujẹ ọkan lo jẹ fun wa pe ẹni naa padanu ẹmi ẹ. To ba jẹ pe o n ba a jẹ naa ni, iyẹn o ni ka ro iku ro o bi ko ṣe ka ba a sọrọ tutu pe ko yee hu iru iwa bẹẹ mọ”.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun dariji ọkunrin naa, ko si tẹ ẹ safẹfẹ rere lode ọrun.