Nitori ẹya ara oku ti wọn ge lọsibitu, nọọsi meji foju bale-ẹjọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọrọ ẹya ara ti wọn ni wọn ji ge lọ lara alaisan kan, Abilekọ Rachael Boluade, ẹni to ku sileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Ibadan Central Hospital, laduugbo Ọṣọṣami, n’Ibadan, ti dẹjọ, awọn ọmọ iya naa ti n ba awọn oṣiṣẹ ileewosan ọhun fa ẹjọ gidi ni kootu.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o ṣe diẹ ti iya agba naa ti n gba itọju nileewosan yii ko too dagbere faye loru ọjọ Abamẹta, Satide ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii, mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji.

Njẹ ki awọn ọmọlooku lọọ gbe oku iya wọn kuro nileewosan yii lọ si mọṣuari, nibi ti wọn maa n tọju awọn oku pamọ si, ki wọn le raaye ṣeto ẹyẹ ikẹyin ati eto isinku iya naa, ni wọn ri i pe wọn ti ṣiṣẹ abẹ si iya wọn lara.

Ṣugbọn iṣẹ abẹ eleyii ki i ṣe iru eyi ti awọn akọṣẹmọṣẹ dokita maa n ṣe, awọn ọmọ eriwo ni wọn dọgbọn ge ẹran diẹ nibi agbari, apa ati ibi kọlọfin ara oku naa.

Nigba ti ọkan ninu awọn ọmọọlooku debẹ lati gbe oku iya wọn lọ ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Aje, Mọnde, lo ri i bi awọn ọmọ aye ti ṣe fọbẹ dara si iya ẹ lorikeerikee ara.

 

Lọgan ni baba naa sọ ọ di ariwo mọ awọn alaṣẹ ọsibitu ọhun lọwọ, ṣugbọn ko sẹni to jẹwọ pe oun mọ nnkan kan nipa iṣẹ abẹ aramọnda naa, n lawọn ẹbi oloogbe ba fi ọlọpaa gbe wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022.

Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) kan, Muibat Ọlatunji, ati Oluwafunmilayọ Omeh, ẹni ọdun mejilelogun (22), ti awọn mejeeji jẹ nọọsi pẹlu awọn meji mi-in, Bamidele Bamiro, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32), to jẹ ọdẹ to n ṣọ ileewosan naa; pẹlu oṣiṣẹ ọsibitu ọhun kan to n jẹ Godwin Omomoh, lawọn ọlọpaa mu gẹgẹ bii afurasi lori ọran naa.

Nigba ti wọn n fara han ni kootu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, ẹsun meji ọtọọtọ ni wọn fi kan wọn niwaju adajọ, wọn ni wọn ko bọwọ fun oku eeyan ẹlẹran ara bii tiwọn, bẹẹ ni wọn ṣe oku alaisan to ku sibi iṣẹ wọn ṣakaṣaka, ṣugbọn gbogbo wọn sọ pe awọn ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun naa.

Amofin Iyabọ Ọladoyin to jẹ agbẹjọro awọn olupẹjọ sọ niwaju adajọ pe awọn olujẹjọ wọnyi pẹlu awọn eeyan kan ni wọn jọ huwa to lodi sofin naa, ṣugbọn mẹrin ti ọwọ awọn agbofinro tẹ ninu wọn lo n jẹjọ yii, nigba ti awọn yooku ti na papa bora.

Amofin George Ọlaniyi ti i ṣe agbẹjọro awọn olujẹjọ ja fitafita lati gba beeli awọn onibaara rẹ. Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Emmanuel Idowu, gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira (₦200,000), ati oniduuro meji, meji ko too sun igbẹjọ naa siwaju.

Leave a Reply