Faith Adebọla, Eko
Oludari agba ijọ Ridiimu kari aye, Pasitọ Enoch Adeboye, ti bẹnu atẹ lu bijọba ṣe jẹ ki akude ba owo ilẹ wa, towo naa waa di pọ-n-tọ lẹgbẹẹ awọn owo ilẹ okeere bii tiẹ, o lọrọ naa buru gidi o, tori ni bayii, Naira ti ya yẹyẹ, koda, beba ti wọn fi n tẹ ẹ niye lori ju owo ti wọn kọ sara beba naa lọ.
Adeboye sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla yii, nigba to n sọ ero rẹ nibi eto ijọsin oloṣooṣu ṣọọṣi RCCG ọhun ti wọn n pe ni Holy Ghost Service, lori bi banki apapọ ilẹ wa, iyẹn Central Bank of Nigeria( CBN) ṣe lawọn fẹẹ paarọ awọn owo Naira kan, wọn lawọn fẹẹ daṣọ tuntun fawọn owo naa, wọn yoo si gbe awọ tuntun wọ laipẹ.
Ọga agba banki apapọ naa, Godwin Emefiele, ti kede ṣaaju pe awọn owo ti wọn fẹẹ paarọ awọ wọn ọhun ni ọgọrun-un Naira, (N100), igba Naira (N200), ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) ati ẹgbẹrun kan Naira (N1,000), ati pe owo tuntun naa yoo gori atẹ lọjọkẹẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun yii.
Ninu ọrọ rẹ, Adeboye ni:
“A nilo aanu Ọlọrun o, afi ka maa tọrọ aanu ẹ gidi, tori nnkan to n lọ lorileede yii, ko tiẹ ba laakaye kankan mu pẹẹ.
“Owo Naira wa o tiẹ waa niye lori to beba ti wọn fi tẹ ẹ. Ebi apamokuu n pa awọn eeyan, ekukaka ni wọn fi n ri owo to to lati ra burẹdi jẹ, ṣugbọn Mose to jẹ aṣaaju awọn eeyan tiwa ko nironu meji ju bi wọn ṣe fẹẹ pa Naira laro lati fi kun ẹwa ẹ si i lọ. Lero tiwọn, bowo yii o ba tiẹ le ra burẹdi, ka ṣaa ti rẹwa daadaa, lo jẹ wọn logun. Ṣe ọgbọn wa ninu iyẹn? Ọlọrun nikan lo le ṣaanu wa ni o.”
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti wọn ti ṣefilọ pipaarọ owo naa ni Naira ti n fojoojumọ ṣubu yakata lẹgbẹẹ awọn akẹgbẹ rẹ bii dọla ati pọun. Lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, iye ti wọn n ṣẹ dọla ilẹ Amẹrika si Naira ti ju ọgọrin Naira lọ.
Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun naa ni titi di ba a ṣe n sọ yii, Ọlọrun o ti i fihan oun pato, bẹẹ ni ko sọ foun boya eto idibo gbogbogboo ọdun 2023 maa waye abi ko ni i waye.
“Ki i ṣe pe mo fẹẹ dẹruba yin o, mi o si sọ fun yin pe mo mọ nnkan aṣiri kan tẹyin yooku ko mọ, mi o ki i ṣe wolii, pasitọ ni mi, ṣugbọn pasitọ yin ni mo jẹ. A ni lati gbadura gidi.
“Ka ṣi maa tẹsiwaju bii pe yoo waye. Ṣugbọn emi Adeboye, tara mi ni mo n sọ o, mi o sọ tẹlomi-in o, Ọlọrun o ti i sọ fun mi pe idibo naa yoo waye. O ṣee ṣe ko sọ ọ fun mi lọla o, mi o mọ, ṣugbọn ni lọwọlọwọ ti mo jokoo siwaju yin yii, Ko ti i sọ ọ fun mi pe eto idibo naa yoo waye lọdun to n bọ abi ko ni i waye.”
Bẹẹ ni Pasitọ Adeboye wi o.