Ọrọ ti Sanwoolu sọ fawọn agbofinro yii, ọrọ gidi ni o

Ni ọsẹ to kọja yii, Gomina Babajide Sanwoolu ipinlẹ Eko ranṣẹ si gbogbo ọlọpaa ati awọn agbofinro ipinlẹ rẹ patapata, o ni ki wọn sinmi lati maa daamu awọn eeyan to n rin jẹẹjẹ wọn lọ loju popo, ati lati maa fi tipatipa gbowo lọwọ awọn eeyan ti ko ṣe kinni kan fun wọn ju pe wọn n rin lọ jẹẹjẹ tiwọn. Laarin awọn ọlọpaa ni Sanwoolu ti sọ bẹẹ, nibi ikẹkọọ-jade wọn kan ni. Ọrọ naa ko deede ja bọ lẹnu gomina yii, awọn iroyin toun naa ti gbọ nipa ohun ti awọn agbofinro wa maa n ṣe ni, paapaa, awọn ọlọpaa, nigba to jẹ awọn ọlọpaa yii ni wọn sun mọ araalu ju lọ. Awọn ni wọn yẹ ki wọn jẹ ọrẹ araalu. Ṣugbọn ọpọlọpọ wọn, ọta araalu ni wọn n ṣe. Nnkan ti bajẹ debii pe awọn ọlọpaa funra wọn n digunjale, abi nigba ti agbofinro ba fi aṣọ ijọba gbowo ipa lọwọ araalu, ki waa niyatọ awọn ati awọn to n digunjale kiri. Bẹẹ, awọn ọlọpaa gidi, awọn ti wọn nibẹru Ọlọrun, ti wọn si mọ iṣẹ wọn bii iṣẹ wa laarin wọn, ṣugbọn awọn eleyii ko pọ bii awọn papanlagi, awọn ti ibẹru Ọlọrun ti jinna si, awọn ti wọn ko laaanu, to jẹ owo ti jaraba aye wọn. Awọn yii ni yoo da ero lọna ti wọn yoo si maa sare wo iye to wa ninu akaunti rẹ. Ti wọn ba si ti ri owo nla nibẹ ti ori wọn yoo yi sodi pata, to jẹ ko ni i si ero miiran lọkan wọn ju bi wọn yoo ti gba owo naa lọ. Obinrin oniṣowo kan fi ẹjọ awọn ọlọpaa yii sun nipari oṣu Kẹsan-an yii, obinrin naa ni awọn kan ti wọn wọ aṣọ bii ologun ja mọto tirela ti oun fi n gbe diisu gba lọwọ awọn dẹrẹba oun to n gbe mọto naa lọ, wọn si ni awọn n gbe mọto naa lọ si ọgba wọn. Wọn gbe dẹrẹba ati ọmọọṣẹ rẹ wọ inu mọto mi-in, wọn si gbe wọn de Too-geeti ki wọn too ja wọn silẹ, bẹẹ Maryland ni wọn ti mu wọn. Igba ti awọn mejeeji pada sare de ibi ti mọto diisu naa wa, wọn ko ba a mọ, wọn ti gbe e lọ, nigba ti wọn yoo si pada ri i, wọn ti ja gbogbo epo diisu to wa nibẹ naa kuro, mọto ofifo ni wọn ri. Nitori ẹ lobinrin yii loun ṣe gba ileeṣẹ ọlọpaa lọ ti oun lọọ sọ fun wọn nibẹ. Awọn ọlọpaa ni ki oun mu owo wa ki wọn le fi tiraaki mọto ti wọn ji yii, wọn si gba ẹgbẹrun rẹpẹtẹ lọwọ ẹ, ṣugbọn o ni wọn ko ba oun ṣe kinni kan, kaka bẹẹ, wọn ni ki oun tun maa mowo wa si i ni. Awọn ti wọn n gbowo lọwọ rẹ ti ri i bii ikoko ọbẹ, wọn si ti mura lati jẹ gbogbo ọbẹ to wa nibẹ tan pata. Nipari oṣu Kẹwaa yii, ọkunrin olorin kan royin bi awọn ọlọpaa ṣe mu oun loju ọna, ti wọn si gba akaunti oun, ti wọn si ni afi ki awọn jọ da owo to wa nibẹ si meji, ki oun ko ọkan, ki awọn naa ko ọkan, nitori awọn ri i pe ọmọ Yahoo ni. O ni oun ni suuru, nitori bi ohun wọn ti le, ati bi wọn ṣe n ṣe hanranhanran soun yẹn, bi oun ba ba wọn ṣe agidi, wọn yoo pa oun sibẹ, wọn yoo si sọ nnkan mi-in fawọn ti ko ba mọ bi oun ti ṣe ku ni. Meloo melo leeyan to ti ku si oko ailẹṣẹ bẹẹ, meloo meloo lawọn to ti ku sọwọ awọn ọlọpaa ti ko dara yii. Ọga ọlọpaa pata paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa yee yẹ foonu ẹni-ẹlẹni wo loju ọna, ki wọn yee da awọn eeyan duro ki wọn maa tu ẹru wọn, ṣugbọn awọn eeyan naa ko gbọ, wọn yoo da ero duro, wọn yoo si sare maa gba foonu lọwọ wọn. Bakan naa ni wọn ni ki i ṣe ojuṣe ọlọpaa lati maa beere iwe mọto loju ọna, ṣibẹ awọn eeyan naa yoo jade, wọn yoo ni awọn n ṣe akanṣe iṣẹ, wọn yoo maa yẹ iwe mọto wo, wọn yoo maa gba foonu, gbogbo ẹ naa, owo lawọn ọlọpaa ti ko dara yii yoo fi gba lọwọ awọn ti wọn ba mu. Awọn ọlọpaa buruku yii n ba awọn ọlọpaa rere to wa laarin wọn lorukọ jẹ, debii pe bayii, ko si ẹni to ri ọlọpaa bii ọrẹ araalu, ṣaaṣa araalu ni wọn ka wọn si, bẹẹ ni wọn ko si ri wọn bii olugbeja tabi iranṣe ọba, wọn ri wọn bii ole ati alọnilọwọgba to n ṣiṣe tara wọn funra wọn, ti wọn n jiṣẹ ti ko sẹni to ran wọn. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ọrọ ti Gomina Sanwoolu sọ yii bọ si asiko, ki awọn ọlọpa gbọ, ki wọn yee daamu araalu, ki awọn ọga wọn si gbọ, ki wọn kilọ fun wọn daadaa. Ọlọpaa ki i ṣe ọta araalu, ọrẹ araalu lo yẹ ki wọn jẹ, ṣugbọn ọpọ awọn ọlọpaa tiwa ni ko dara, alọnilọwọgba ni wọn o. Ṣugbọn ẹ gbọkilọ ti Sanwoolu ṣe, ẹ yiwapada, kaye ẹyin naa le daa!

 

Leave a Reply