Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ọfọ nidile Babalọla, laduugbo Soka, n’Ibadan, wa bayii pẹlu bi ile ti wọn n kọ lọwọ ṣe wo lu ọmọkunrin wọn kan, to si ṣe bẹẹ jẹ Ọlọrun nipe.
Iru iku to pa Babalọla yii ni iba tun pa ọkunrin kan to n jẹ Ṣẹgun Abayọmi naa ti ile ọhun tun wo lu, ṣugbọn ti ori ko o yọ lọwọ iku, amọ to fara bo fẹlẹfẹlẹ.
Lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti ileetaja ti wọn n kọ lọwọ ọhun, eyi to wa lẹyin ileepo Halleluyah, laduugbo Soka, n’Ibadan, wo lu eeyan meji, ti ọkan ba ibẹ ku, ti ekeji si fara pa yannayanna.
Gẹgẹ bi awọn araadugbo naa ṣe fidi ẹ mulẹ, eyi kọ nigba akọkọ ti apa kan ile ti wọn ko ti i kọ tan ọhun yoo wo lulẹ, ṣugbọn to jẹ bo ṣe n wo ni wọn n tun un kọ, to fi di pe o wo paayan lọtẹ yii.
Awakọ ileeṣẹ aladaani kan n’Ibadan ni wọn lo ni ile itaja to n wo ni gbogbo igba yii.
“Ki i ṣe awọn to mọ nipa iṣẹ ile kikọ lo n kọ ile yẹn. Koda, ko si ẹnjinnia to n mojuto o, Alaaji to ni in naa lo n mojuto nnkan rẹ, ki i ṣe ẹnjinnia to jẹ akọṣẹmọṣẹ”, bẹẹ lọkunrin kan to n gbe Soka, nitosi ile ọhun sọ.
Ọkunrin naa ti waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati waa ṣewadii nipa awọn to n kọ ile ọhun, ki wọn si fofin de wọn bi wọn ba ri i pe wọn ki i ṣe akọṣẹmọṣẹ abanikọle lati dena iru iṣẹlẹ buruku bẹẹ lọjọ iwaju.