Miliọnu mẹwaa Naira lawọn ajinigbe fẹẹ gba ki wọn too gbe oku ọkunrin ti wọn pa sọdọ wọn silẹ

Monisọla Saka

Awọn ọdaju ajinigbegbowo ilẹ Hausa kan ti n beere fun miliọnu mẹwaa Naira(10m) gẹgẹ bii owo itusilẹ fun oku ọkan lara awọn ti wọn ji gbe, Obadiah Ibrahim, niluu Kaduna, lọsẹ bii meloo kan sẹyin, to si ku sakata wọn.

Ọkan lara awọn mọlẹbi ẹni ti wọn ji gbe yii to tun jẹ aburo ẹ lọkunrin, Kefas Obadiah, ṣalaye pe awọn agbebọn yii ti kọkọ gba miliọnu mẹta Naira, ṣugbọn wọn ta ku jalẹ, ti wọn ko gbe oku ọkunrin ti wọn ti jigbe lati inu oṣu Kẹwaa naa silẹ fawọn.

O ni, “Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to lọ lo ti jade laye ti awa ko mọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni wọn si too sọ fun wa. Nigba ta a beere oku ẹ ni wọn sọ pe ka lọọ wa miliọnu mẹwaa wa ta a ba mọ pe a ni oku rẹ ẹ gba, wọn lawọn o le ṣiṣẹ ọfẹ fun wa”.

Nigba to n ṣalaye gbogbo idaamu ati wahala toju awọn mọlẹbi ti ri lati igba ti ẹgbọn wọn ti dawati, o ni, “Obadiah Ibrahim lorukọ ẹgbọn mi yẹn. Ni ibẹrẹ oṣu Kẹwaa, ọsẹ akọkọ, ninu oṣu Kẹwaa, gan-an ni wọn ji i gbe lagbegbe Sabon Gaya, lasiko to n dari bọ lati ilu Abuja, to n pada lọ si Kaduna. Loootọ ki i ṣe emi ni mo n ba awọn ajinigbe yẹn sọrọ o, o leeyan kan to n ba wa dunaadura nitori miliọnu lọna igba Naira (200m) ni wọn kọkọ beere fun ka too fi ọpọlọpọ ẹbẹ na an de ori miliọnu mẹta ati diẹ.

Wọn sọ ibi ta a maa gbe owo wa fawọn, lẹyin ta a fun wọn lowo itusilẹ yii tan ta a n reti ki wọn da eeyan wa silẹ ni wọn sọ fun wa pe owo ounjẹ leyi ta a mu wa yẹn, pe o si ti tan, ka lọọ wa miliọnu lọna mẹẹẹdogun (15m) mi-in wa.

Nigba to tun ya, wọn pada tun ja a walẹ si ẹgbẹrun marun-un (5m) fun wa, pẹlu ọkada mẹta, ṣugbọn ọkada kan ni wọn pada gba lọwọ wa. Lẹyin ti wọn tun gba ọkada tan, la o ba tun gburoo wọn mọ, gbogbo ọna la wa lati ba wọn sọrọ, amọ pabo lo n ja si.

“Igba to si tun ya tẹni to n ba wa ṣe idunaadura tun pe wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọfọ iku bọda wa ni wọn tu fun wa. Ere la kọkọ pe e, lawa ba tun n pe wọn pe boya wọn n ṣawada lasan ki ọkan wa le ko soke, ti wọn tun maa fiyẹn rowo mi-in gba lọwọ wa ni. Bi wọn ṣe n dun mọhuru mọhuru mọ ẹni to n ba wọn sọrọ niyẹn pe awọn maa tọpinpin ibi ta a wa, awọn aa dẹ wa gbe e ta o ba yee pe awọn.

Wọn lawọn ọlọpaa naa ko awọn eeyan awọn, wọn de wọn mọ igi, wọn si pa wọn. Ibinu iyẹn lawọn naa si fi kanra mọ ẹgbọn tiwa tawọn fi pa a danu”.

Bayii ni aburo oloogbe ṣalaye gbogbo ilakaka wọn lati gba ẹgbọn wọn jade laaye ati alaafia, ṣugbọn ti wọn tun n halẹ mọ wọn lati gbe obitibiti owo wa ti wọn o ba fẹ ki oku eeyan wọn di ounjẹ fun ẹyẹ ati ẹranko igbo.

Kefas ṣalaye siwaju si i pe wọn tun n forukọ Ọlọrun bura pe tawọn ba le fowo yẹn ranṣẹ ni kiakia, laarin ọjọ mẹta lawọn maa yọnda oku fawọn nitori awọn o le ṣiṣẹ ti ko lowo ninu fawọn. O ni ọmọ ọdun mẹrinlelọgbọn (34) lẹgbọn awọn nigba to jade laye lọjọ keje, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

 

Leave a Reply