Wọn ti mu babalawo ati ọmọ ‘yahoo’,  ẹya ara eeyan ni wọn ba lowọ wọn

Faith Adebọla 

Gende kan tẹnikan o ti i mọ orukọ ẹ, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ bayii, oun ati babalawo ẹ, Ọgbẹni Ike, tawọn eeyan mọ si Ọgẹnẹsu, ni wọn ti dero ahamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ibi ti wọn ti n wa eeyan ti wọn fẹẹ fi ṣetutu ọla ni wọn ti mu wọn, bẹẹ ni wọn tun ba oku eeyan kan ti wọn ti pa nile babalawo naa.

Ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago marun-un kọja ogun iṣẹju, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lawọn ọlọpaa to n yẹ ọkọ wo nirona kan lagbegbe Obiaruku, da ọkọ ayọkẹlẹ ti afurasi ‘ọmọ Yahoo’ ọhun n wa lọ, duro, ṣugbọn dipo ti iba fi duro, niṣe lo ṣina bolẹ, to n sa lọ. Eyi lo mu kawọn ọlọpaa naa fura si i, lawọn naa ba gba fi ya a.

Ẹnikan tọrọ ọhun ṣoju rẹ sọ funweeroyin Punch pe nigba tawọn agbofinro naa le e ba, wọn yẹ ọkọ rẹ wo, ni wọn ba ri iwe kan ti wọn kọ ọ sibẹ pe o ni lati wa ori eeyan, apa ati ẹsẹ eeyan tutu wa fun oogun owo to loun fẹẹ ṣe, bẹẹ Yoruba bọ, wọn lẹni ti yoo lo ori ahun atẹsẹ ahun, odidi ahun ni tọhun yoo ra.

Wọn bi i leere ohun to fẹẹ lo awọn nnkan naa fun, o ni etutu kan bayii ni, ko si sọ itumọ etutu naa fun wọn.

Awọn ọlọpaa wọ ọ de teṣan wọn, lẹyin naa ni wọn lọọ gba iwe aṣẹ lati lọọ yẹ ile rẹ wo lọjọ keji. Lẹyin ti wọn gbọn yara mẹta to n lo naa yẹbẹyẹbẹ, wọn ni wọn tun ri iwe mi-in to fara jọ ti akọkọ,  ẹya ara eeyan bii ori, ẹsẹ, apa leyi naa n beere pe ko mu wa.

Ibẹ lọkunrin yii ti jẹwọ pe babalawo oun, iyẹn Ike ‘Ọgẹnẹsu’ lo kọwe naa foun, o loun lo ni awọn nnkan toun gbọdọ wa wa lati fi ba oun ṣoogun owo niyẹn. O ni ẹni ti oun yoo lo ori, apa atẹsẹ ẹ loun n wa kiri tawọn ọlọpaa fi da oun duro lọna lọjọsi.

Lọjọ keji, ọkunrin naa mu awọn agbofinro lọ sọdọ babalawo rẹ yii, wọn tu ile rẹ, wọn o ri nnkan kan, ṣugbọn bo ṣe ku diẹ ki wọn jade ni oorun buruku kan bu tii lu wọn, babalawo naa si ṣalaye pe oun ni odo ẹja kan ninu ọgba oun, awọn ẹja to ku toun yọ sọnu lo jẹra lapa ibi kan nibẹ, eyi to ṣokunfa oorun ọhun.

Awọn ọlọpaa ni ko mu awọn debẹ, wọn si ri apo lailọọnu nla kan lẹgbẹẹ odo ẹja naa loootọ, ni wọn ba tu u, ṣugbọn dipo ẹja jijẹra, oku eeyan ni wọn ba nibẹ to ti jẹra, bi wọn tun ṣe wo ọọkan ni wọn tun ri ori eeyan to n jẹra nibi to wọn ko oku ẹja mi-in si, wọn ni tori kawọn aladuugbo ma baa tete fura lo ṣe n ko oku ẹja sibẹ pẹlu, lati fi oorun ẹja bo teeyan mọlẹ.

Wọn mu babalawo naa, pẹlu ori eeyan ati iyooku oku to jẹra ọhun, ati ọmọ Yahoo to fẹẹ ṣoogun owo, gbogbo wọn ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ fun iṣẹ iwadii to lọọrin, ki wọn too taari wọn sile-ẹjọ.

Leave a Reply