Ko sẹni to koriira Tinubu, oun ni ko yẹra ẹ wo

Ọrọ to kun ẹnu awọn ti wọn n tẹle Aṣiwaju Bọla Tinubu ni pe Yoruba ko fẹran ọkunrin Jagaban yii. Bi wọn ba maa wi, Yoruba lọta Yoruba, Yoruba ko fẹ ki Tinubu di aarẹ, bẹẹ ọmọ ẹni ko le ṣedi bẹbẹrẹ, ka fi ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomi-in ati awọn ọrọ bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn eeyan yii ko bi ara wọn leere pe ṣe Tinubu funra ẹ fẹran Yoruba ṣa! Tabi kawa naa beere pe ṣe Tinubu ka ẹya Yoruba si kinni kan ṣaa! Ṣe ẹmi awọn ọmọ Yoruba jẹ nnkan kan loju oun naa bi!

Ki i ṣe oni, ki i ṣe ana, to jẹ ti nnkan aburu kan ba ti ṣẹlẹ si Yoruba, ọkunrin yii yoo yi oju rẹ si ẹgbẹ kan ni, yoo ṣe bii ẹni pe oun ko mọ, tabi pe oun ko gbọ pe kinni kan n ṣẹlẹ si Yoruba, yoo si maa ba tirẹ lọ. Ṣugbọn to ba jẹ ilẹ Hausa ni ọrọ yii ti ṣẹlẹ, ere lẹlẹ ni yoo sa lọ sibẹ, ti yoo fun wọn lowo, ti yoo lọọ ba awọn gomina ibẹ lalejo, ti yoo ni oun waa ba wọn kẹdun, ara oun bu maṣọ.

 

O ṣoju mi koro ti duro titi lati ọjọ ti wahala awọn ajinigbe ti tun bẹrẹ pada nilẹ Yoruba, paapaa lati ọjọ ti ọrọ awọn ajinigbe lọna Ibadan si Eko ti ṣẹlẹ. Gbogbo ilu pata lo n pariwo, ọrọ naa si jẹ nnkan ibanujẹ fun ọpọlọpọ eeyan. Awọn Fulani ajinigbe ti gba ọna oko, wọn gba ọna odo lọwọ awọn eeyan, wọn n ji awọn eeyan wa gbe gbowo, wọn si n pa awọn mi-in ti ko ba rowo san.

Odidi igbakeji ọga agba Yunifasiti Ibadan wa ninu awọn ti wọn ji gbe, ati awọn ọmọleewe, ati awọn oniṣowo to n ba kata-kara tiwọn lọ. Ọrọ naa mu inira, ibẹru ati aibalẹ ọkan ba gbogbo ilẹ Yoruba pata, nitori ọna marose Eko si Ibadan yii jẹ ọna gbogbo ilẹ Yoruba pata, nitori ọna marosẹ Eko si Ibadan yii lọna to ṣe pataki ju lọ ni gbogbo agbegbe naa, ati ni Naijiria paapaa. Ọrọ naa si kan gbogbo ọmọ Yoruba patapata.

Ṣugbọn Tinubu pẹlu awọn ti wọn n polowo rẹ sinu beba, sinu redio ati lori ẹrọ ayelujara ko ṣe bii ẹni pe wọn wa niluu, kampeeni to n ṣe lo n ba kiri, oun naa si ni awọn ọmọ ẹyin rẹ n tẹle: bo ṣe jẹ oun ni baba, to jẹ oun lo kan, to jẹ oun lo le ṣe e, ariwo alainilaakaye ti wọn n pa kiri niyẹn.

Bi eeyan ba n mura lati ṣe olori ilu, tabi lati jẹ aṣaaju awọn eeyan, idunnu wọn ni yoo maa wa, nigbakigba ti ohunkohun ba si ṣẹlẹ to jẹ nnkan ibanujẹ, tọhun gbọdọ jẹ ki wọn ri oun laarin wọn. Bi ajalu ba ba ilu, olori, tabi ẹni to n lakaka lati di olori ilu yoo sare sọdọ awọn eeyan lati rẹ wọn lẹkun, to ba si jẹ eyi to yẹ ko ba wọn pe ijọba lati tete waa ran wọn lọwọ, tọhun yoo ṣe bẹẹ, awọn araalu yoo si ri gbogbo ohun to ṣe.

Eyi ni i jẹ pe olori tabi aṣiwaju kan fi ifẹ han si awọn eeyan rẹ, ifẹ to ba si fi han sawọn eeyan yii lawọn naa yoo da pada fun un. Bi Tinubu ba fẹ ki Yoruba fẹran oun, oun naa yoo se daadaa fun ilẹ Yoruba, gbogbo aye yoo si ri i. To ba ṣe daadaa fun Yoruba, oun naa yoo ri ifẹ ti awọn eeyan yoo ni si i, bẹẹ ni ki i ṣe pe oun ni yoo beere lọwọ wọn.

Ọtọ ni ki wọn ni eeyan lawọ, ko maa fun ẹnikọọkan to ba de sakaani ẹ lowo, ki awọn yẹn si tori pe o n fun wọn lowo ni kọrọ, ki wọn fẹẹ tori ẹ ku si i lọrun, ki wọn fẹẹ tori ẹ maa parọ fun gbogbo ilu pe eeyan daadaa ni. Ṣugbọn ọtọ ni keeyan ṣoore ti yoo kari gbogbo ilu, ti gbogbo aye yoo si ri i pe ilu ni tọhun n ṣoore fun, ki i ṣe awọn ti wọn yoo sọ ọ di oriṣa akunlẹbọ nitori pe o kọle fun wọn tabi to ra mọto fun wọn.

Bi Tinubu ti lowo to, to si ni agbara oṣelu to, to ba na an fun wọn nilẹ Yoruba, ti ọrọ aje wọn dara, to so gbogbo ọmọ Yoruba papọ, ki i ṣe oun ni yoo ni ki wọn fẹran oun, gbogbo ilu ni yoo fẹran rẹ nitori ohun to ṣe fun wọn. Wọn jiiyan gbe lọna Ibadan si Eko, ko sọrọ, wọn paayan ni Ọwọ, ko wi kinni kan, wọn n ko wọn lẹru l’Oke-Ogun, o ṣe bii ẹni pe oun ko gbọ, awọn oponu kan si jokoo sibi kan, wọn ni Yoruba ko fẹran rẹ, ṣe oun naa fẹran Yoruba ni!

Bi ẹ ba si wi, wọn yoo ni o fi n tan awọn Hausa jẹ ni, pe to ba wọle, o mọ ohun to le ṣe fun Yoruba! Iru ironu odi wo niyẹn! Ṣebi bi wọn ti wi lasiko Ọbasanjọ ni 1999 ree, ti wọn lo n tan awọn Hausa-Fulani ni, to ba depo, aa ṣe Yooba loore. Titi ọdun mẹjọ Ọbasanjọ, oore wo waa ni Yoruba le tọka si pe Ọbasanjọ ṣe awọn, ṣebi kaka bẹẹ, o sọ ara rẹ di Baba Naijiria, eyi to si ṣe lati tubọ fa Yoruba sẹyin ni i joun; ẹnu ẹ la wa titi doni. Ta lo waa sọ pe ti Tinubu ko ni i buru ju bẹẹ lọ!

Ẹni ti ko ba le gbeja awọn eeyan ẹ ni gbangba, ti ko le ran wọn lowọ nigba iṣoro, iyẹn ko fẹran awọn ẹya naa ni! Ki i ṣe Yoruba ni ko fẹran Tinubu o, ẹyin alatẹnujẹ ọmọ tifunlọran to yi i ka ni kẹ ẹ sọ fun un koun naa yẹra ẹ wo, bi aṣaaju kan ba fẹran Yoruba, Yoruba yoo fẹran tọhun dandan!

Leave a Reply