Monisọla Saka
Oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP nipinlẹ Eko, Dokita Ọlajide Adediran, tawọn eeyan mọ si Jandor, ti bu ẹnu atẹ lu nnkan to ni ijọba ipinlẹ Eko sọ nigba to n pe awọn ẹya kan ti wọn n gbe niluu Eko ni ọdaran paraku ti wọn n fiṣẹ ọkada huwa ọdaran wọn. O sọ eleyii latari ofin tijọba fi de ọkada gigun lawọn ibi kan l’Ekoo lasiko to n ba awọn oloye Hausa (Arewa Chiefs), sọrọ laafin Sarkin Hausawa ipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
Jandor loun mọ iṣoro tawọn ẹya Hausa n koju nipinlẹ Eko, bẹẹ lo ṣeleri lati pese ayika to dara fun idagbasoke iṣẹ wọn toun ba depo.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ki i ṣe nnkan to bojumu ni fun ijọba lati ro pe awọn eeyan yin n fi ọkada ṣe awọn iṣẹ ibi kan. Gbogbo awọn ẹya to wa l’Ekoo yii ni ọdaran wa laarin awọn naa, ki i ṣe awọn eeyan yin nikan.
Ti n ba di gomina, dipo ki n fofin de ọkada gigun, ma a jokoo pọ pẹlu awọn aṣaaju Hausa lati le sọrọ lori ba a ṣe fẹẹ yọ awọn kanda inu irẹsi laarin awọn to n fi ọkada wiwa ṣiṣẹ ṣe, ka si fiya jẹ awọn to ba ṣẹ si ofin ju ka gba ijẹ lẹnu wọn lọ.
“Ijọba APC o mọ riri ipa pataki tẹ ẹ n ko ninu ilọsiwaju ati idagbasoke eto ọrọ aje ipinlẹ yii, nitori bẹẹ ni gomina ṣe paṣẹ pe ki wọn da iṣẹ ọkada duro niluu Eko lai wa iṣẹ mi-in fi di i fawọn eeyan yin.
Mo waa fi n da yin loju pe ijọba mi o ni i ṣe bii tiwọn yii laelae. A maa jokoo sọrọ lori ọna ta a le gba rẹyin gbogbo kudiẹ-kudiẹ to ba n tibi iṣẹ ọkada yọ ni.
Ti mo ba wa wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ yii, awọn eeyan apa Ariwa to n gbe niluu Eko maa ri anfaani lati ṣiṣẹ pẹlu iṣakoso mi yatọ si iwe igbanisiṣẹ ẹyọ kan ṣoṣo tawọn to wa nibẹ lọwọ bayii n fun yin pẹlu bẹ ẹ ṣe ti lo to ọgbọn ọdun nipinlẹ naa.
Ọkan ninu adari awọn Hausa l’Ekoo, Waziri Shuwa-Arabs, Sheik Adam Muhammed, ninu ọrọ tiẹ, rọ oludije dupo gomina naa lati ma ṣe jẹ ki eti awọn di si bi nnkan ba ṣe n lọ to ba dori ipo, bẹẹ ni wọn tun beere nnkan tawọn maa jẹ lere tawọn ba ti i lẹyin.
Muhammed waa sọrọ lorukọ gbogbo awọn eeyan ẹ pe ti Jandor ba wọle gẹgẹ bii gomina, ipo kọmiṣanna marun-un, ati ti alaga kansu (councillor) mẹtadinlọgọta (57) lawọn n fẹ ko fun awọn.