Faith Adebọla, Eko
Ẹkọ o ti i ṣoju mimu ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, paapaa laarin awọn agbaagba ẹgbẹ naa loke, pẹlu bawọn gomina marun-un tinu n bi, atawọn alatilẹyin wọn ko ṣe ti i yi ipinnu wọn pada titi di ba a ṣe n sọ yii lori bi ọn ṣe ni aọn ko ni i ṣatilẹyin fun oludije wọn, Alaaji Atiku Abubakar lasiko ibo ọdun to n bọ. Arọni o wale, onikoyi o sinmi ogun, lọrọ naa da laarin wọn, bẹẹ si lọkan awọn ọmọ ẹgbẹ ko balẹ, tori wọn ni airinpọ lo n jẹ ọmọ ejo niya.
Nibi ipade pataki kan to waye laarin awọn gomina ipinlẹ maraarun ọhun ti wọn n jẹ (G-5) ti wọn ya ara wọn sọtọ pe awọn ko ni i ba Atiku ṣe, ti ko ba yọ alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu, ko si fi ẹlomi-in to wa lati iha Guusu orileede yii rọpo rẹ, gẹgẹ bii adehun ti wọn jọ ṣe, lọrọ yii ti jẹ yọ.
Awọn gomina ọhun ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ti ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ati Gomina ipinlẹ Abia, Victor Ikpeazu.
Lara awọn mi-in ti wọn fara mọ ipinnu awọn gomina marun-un yii ti wọn si pesẹ sipade naa ni gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹri, Oluṣẹgun Mimiko, ti Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti Cross-River nigba kan, Donald Duke atawọn eekan eekan ẹgbẹ PDP lati iha Guusu lọhun-un.
Igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ naa tẹlẹ, Oloye Ọlabọde George lo gba wọn lalejo, otẹẹli Southern Sun, iyẹn Ikoyi Hotel atijọ, nipade naa ti n waye.
Lopin ipade, wọn ko mu atẹjade kankan jade, amọ Mimiko ati Wike to ba awọn ọmọ ẹgbẹ PDP sọrọ sọ pe awọn maa ṣiṣẹ fun gbogbo awọn oludije ẹgbẹ naa, bẹrẹ latori gomina, sẹnetọ atawọn ipo yooku latoke delẹ, ṣugbọn ko mẹnu ba oludije funpo aarẹ, tabi Atiku.
Ọrọ yii ko tẹ ọpọ awọn ero to pẹjọ naa lọrun rara, ọpọ wọn lo si fi aidunnu wọn han si iṣẹlẹ naa.