Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti paṣẹ pe ki gbogbo asunwọn owo ipinlẹ naa di titi pa bayii.
Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ nibi ayẹyẹ ti wọn ti bura fun un gẹgẹ bii gomina alagbada kẹfa nipinlẹ Ọṣun, eyi to waye laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo ti ṣeleri pe opin yoo de ba oniruuru awọn iwa ibajẹ atawọn iwa ta-ni-yoo-mu-mi ti ẹgbẹ oṣelu APC ti hu kọja nipinlẹ naa.
O ni ko si nnkan to n jẹ ipinlẹ Ọmọluabi (State of the Virtues) mọ, ipinlẹ orisun iye (State of the Living Spring) to ti wa tẹlẹ ni ki wọn bẹrẹ si i lo pada bayii.
Bakan naa, bi ijọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ṣe yi orukọ ipinlẹ Ọṣun pada si State of Ọṣun ni Adeleke sọ pe ko ba ofin mu, o ni ki ohun gbogbo pada si Ọṣun State bo ṣe wa tẹlẹ.
Lori gbogbo igbesẹ ti gomina ana, Adegboyega Oyetọla, gbe lẹyin to ti fidi-rẹmi ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, Gomina Adeleke ni ko si eyi to le duro nibẹ, o ni ki ohun gbogbo pada si bo ṣe wa ṣaaju ọjọ idibo ọhun.
Nitori idi eyi, Adeleke sọ pe oun yoo gbe awọn igbimọ kan kalẹ lati ṣayẹwo oniruuru awọn igbesẹ ijọba Oyetọla bii iyansipo awọn eeyan, igbani-sisẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, o ni ohunkohun to ba jẹ abajade igbimọ naa nijọba yoo ṣiṣẹ le lori.
O fi da awọn oṣiṣẹ, awọn aṣofin, ẹka eto idajọ ati bẹẹ bẹẹ lọ loju pe ijọba oun yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu wọn, igbaye-gbadun wọn yoo si jẹ iṣejọba oun logun.