Ibọn onike lobinrin yii fi n digun jale ni Mowe

Gbenga Amos, Ogun

 Niṣe lawọn eeyan adugbo kan sare janna-janna lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Mowe lalẹ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla yii, nigba tawọn adigunjale kan ya bo ileetaja nla ti wọn ti n ta awọn nnkan tẹnu n jẹ bii irẹsi, ẹwa ati gaari, to wa ni ikorita Safari, ni Adesan, ti wọn yọ ibọn si wọn, ti wọn si bẹrẹ si i ko owo ọja tawọn oniṣọọbu naa ti pa lọjọ naa atawọn ọja iyebiye.

Amọ loju-ẹsẹ ti DPO tẹsan ọhun, SP Fọlakẹ Afẹnifọrọ, ti gbọrọ yii lo ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ pe ki wọn lọọ koju awọn adigunjale ọhun, awọn ẹṣọ alaabo So-Safe Mowe kan tẹle wọn lọ, ọwọ si ba wọn. Iyalẹnu ni pe obinrin-binrin, Chioma Okafor, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, loun ati ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Joshua Nweke, wa nidii iwa buruku naa, ohun to si jọ-ọ-yan loju ju ni pe nigba ti wọn mu wọn, ti wọn yẹ ara wọn wo, ibọn ti wọn mu dani, tawọn ero to wa nileetaja naa ri ti wọn fi doju bolẹ pẹlu ibẹru-bojo, ibọn naa ki i ṣe ibọn gidi, ibọn onike ni, amọ bi wọn ṣe ṣe e, ko sẹni to le mọ pe ki i ṣe ojulowo, tori niṣe lo n kọ yanran, o si jọ ojulowo ibọn gan-an.

Nigba ti wọn ṣewadii lẹnu wọn, Nweke jẹwọ pe Chioma lo mu erongba pe kawọn maa digun jale wa, o ni ọna to ya kiakia tawọn fi le tete maa ri owo na niyẹn, ọsẹ keji to mu amọran naa wa lo ra ibọn onike wale, o ni ibọn naa lawọn aa maa lo, o si kọ oun ni ọrọ tawọn maa sọ, boun ṣe maa di ibọn naa mu, ati bawọn ṣe maa fi i halẹ mọ awọn eeyan nibikibi tawọn ba ti fẹẹ jale.

O loun o ti i tẹle e lọ soko ole ri, akọkọ toun maa lọ naa lọwọ tẹ awọn yii.

Wọn ni nigba tawọn afurasi ọdaran yii wọ ṣọọbu to jẹ Ọgbẹni Johnson Nwokoro ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ naa, niṣe ni wọn kọkọ ṣe bii ẹni to fẹẹ ra irẹsi at’ẹwa, tawọn naa dara pọ mọ ero to n na ọja, ojiji si ni wọn fabọn yọ, ti wọn ni kawọn ero doju bolẹ, ko si sẹni to le ko wọn loju, tori o ba wọn labo, ati pe ibọn lapati kò lapati, kò sẹni to maa fẹ ki wọn doju ẹ kọ oun, ni wọn ba paṣẹ fun onileetaja na lati rọ owo to pa da sawọn lapo.

Ṣa, awọn mejeeji ti wa lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa l’Eleweẹran, Abẹokuta, gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun , CP Lanre Bankọle ṣe paṣẹ.

Ọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n gbogun ti iwa idigunjale ati ijinigbe ni wọn wa, ti wọn n ran wọn lọwọ lẹnu iwadii wọn.

Wọn ni lẹyin iwadii ni wọn maa too foju wọn bale-ẹjọ.

Leave a Reply