Ko sẹni kan to fẹsun egboogi oloro gbigbe kan Atiku bii ti alatako rẹ – Melaye

Monisọla Saka

Agbẹnusọ ikọ onipolongo ibo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Dino Melaye, ti sọ pe lara nnkan to yẹ kawọn fi maa yangan ni pe ko si awuyewuye kankan nilẹ lori oludije ẹgbẹ awọn, Atiku Abubakar, bii ti alatako rẹ to n dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, to jẹ pe ojumọ kan, akaimọye iroyin odi nipa ẹ ni, ti ẹsun si kun ọrun ẹ bamu.

Lasiko ifọrọwerọ to ṣe lori tẹlifiṣan Channels, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii, lo ti sọ pe ko sẹni to ti i pariwo Atiku sita pe ogbologboo ọga awọn elegboogi oloro ni, tabi pe o ti bẹrẹ si i maa ṣarán, gẹgẹ bi Tinubu ṣe maa n sọ kantankantan lẹnu kiri ode.

O ni, “Atiku gẹgẹ bii ẹni kan ko lẹbọ lẹru, ko sohun to pamọ nipa ẹ tẹ ẹ ko ni i ri ka ninu itan igbesi aye ẹ. Kẹ ẹ ka itan igbesi aye ẹ ni nnkan bii ọgbọn ọdun sẹyin, eeyan kan naa lo ṣi n ba wi titi di ọla tẹ ẹ ba tun lọọ tun un yẹ wo. Ẹ lanfaani lati mọ awọn ẹgbẹ ẹ nile ẹkọ, ileewe to lọ, koda ibi to ti wa, nitori ko si awuyewuye kankan nipa Atiku Abubakar.

Ṣugbọn gbogbo nnkan to rọ mọ Tinubu, kayeefi to ka ni laya ni, nitori ojoojumọ leeyan n gbọ iroyin awọn nnkan to n ṣe ni ni haa-hin-in nipa ẹ.

“Atiku ko ni aṣiri ikọkọ kankan teti o gbọdọ gbọ, ko sẹni kan to waa naka si i pe agba ọjẹ ninu awọn to n fi egboogi oloro ṣiṣẹ ṣe ni, tabi pe o ti jingiri ninu lilo oogun oloro, bẹẹ ni ko jade sita ko maa sọ awọn nnkan ti ko jọra wọn bii ẹni ti ogbo ti sọ di ẹni to n ṣe arán.

Eyi to waa ti ni loju ju ninu gbogbo ẹ ni pe, nigba ti iya to bi Bọla Ahmed Tinubu ku lọdun diẹ sẹyin, nitori pe ọmọ ti pa orukọ da lẹyin odi, ti ko si da ara ẹ loju, ko debi oku iya ẹ ki awo ma baa ya, nnkan itiju ati ibanujẹ to ju iyẹn lọ fun abiyamọ ko tun si mọ”.

Melaye tun ṣapejuwe Tinubu gẹgẹ bii ẹni ti ọpọlọ ati iduro rẹ ko yẹ fun ipo aarẹ.

“Eeyan ti iduro rẹ o ba lẹsẹ nilẹ, ti ọpọlọ rẹ o si pe daadaa, tabi to ti n yara gbagbe nnkan ko tẹle ofin ilẹ Naijiria ọdun 1999, nitori ohun tofin yẹn sọ ni pe keeyan too le di aarẹ orilẹ-ede yii, ara tọhun gbọdọ pe perepere, ko duro ire, ki ọpọlọ ẹ paapaa si wa nipo to yẹ, nidii eyi, igbesẹ Tinubu n ta ko ofin ni”.

O tẹsiwaju pe, ki i ṣe iru ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo tun rẹni dibo fun wọn mọ lẹyin ti wọn ti ja awọn eeyan naa kulẹ lati pese eto ijọba to mọyan lori fun wọn.

O ni nnkan to n ka oun lara ni pe nilẹ Naijiria yii nikan ni awọn ẹgbẹ APC pẹlu iwa ọdaju ati eleṣu wọn, ipaniyan, ijinigbe, inira, ebi, iṣẹ ati iya ti wọn ko ba awọn araalu tun ti lori laya lati jade sita pe ki wọn dibo fawọn, ti wọn si tun duro lati ṣatako eeyan to dangajia, tori rẹ pe perepere, ti ọpọlọ ẹ ko si ṣiṣẹ idakureku.

Leave a Reply