Nitori Tinubu, Ọlaiya Igwe bọra ẹ sihooho leti okun

Jọkẹ Amọri

Tiyanu tiyanu lawọn eeyan n fi n wo fidio ọkan ninu awọn agba oṣere ilẹ wa nni, Ẹbun Oloyede ti gbogbo eeyan n pe ni Igwe, to gbe sori ikanni Instagraamu rẹ. Ṣe ki i kuku ṣe pe ọkunrin naa ṣẹṣẹ n gbe fidio jade, nigba to ṣe pe iṣẹ to yan laayo niyẹn. Ohun to mu iyanu wa ninu fidio to gbe jade yii ni pe ihooho ọmọluabi ni ọkunrin ti wọn n pe ni Ọlaiya Igwe yii wa leti okun, ko si tori ọrọ ara rẹ lo seti okun yii lọọ gbadura o, oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu, lo tori ẹ lọ seti okun. Tori ọkunrin oloṣelu to ti figba kan ṣe gomina Eko yii ni Ọlaiya ṣe bọ ara rẹ sihoohoo ọmoluabi, lo ba wọle adura kikan kikan bii tawọn ẹlẹmii.

Ninu fido naa ni Ọlaiya ti kawọ rẹ mejeeji soke nihooho ọmọluabi, leti omi okun naa, to si da bii pe aara n san, oun wa laarin aara to n san naa, o si gbe fọto Tinubu sibi fidio to ṣe ọhun. Bẹẹ lo gbe ti Sanwoolu ati Igbakeji rẹ, Babafẹmi Hamsat si i. Lo ba na ọwọ rẹ mejeeji siwaju, lo ba kiri mọ adura ti a n wi yii nihooho, o ni,  ‘Oluwa ooo, Oluwa atobiju Ọba iyanu, Ọba lanaa, Ọba lonii, Ọba lọjọ aye gbogbo, mo pe Ẹ, emi Ẹbun, Lukman Ẹbun Oloyede, Ọlaiya Igwe, mo waa pe Ẹ, mo waa sa diẹ. A ki i ridii okun, a ki i ridii ọsa, a ki i ridii ọmọ nigelege. Ọlọrun Ọba o, Tori Bọla Ahmed Tinubu ni mo ṣe waa pe ẹ, Bọla Ahmed Tinubu, jẹ ko jawe olubori Ọlọrun, ba waa gbe e depo. Mo diidi wa si eti okun lati waa bẹbẹ fun iwọ Ọlọrun Ọba alaanu ju lọ ni. Bi omi okun yii ṣe pọ to, bẹẹ ni ki ibo Bọla Ahmed se pọ to, bi omi okun yii ṣe pọ to, bẹẹ ni ki ibo Bola Ahmed se pọ to. Ma jẹ koju ti wa, ma jẹ ki oju ti Akanbi, Akanbi ọmọ olodo idẹ, Bọla Ahmed Jagaban, oun ni ko o jẹ ko jawe olubori, ko di presidenti orileede Naijiria. Iya to n jẹ wa, iwọ Ọlọrun, waa ka gbogbo iya yii kuro. Mo diidi wa, mi o le sun mọju, mi o le sun mọju, mi o le sun, mi o le wo….’’

Bi Ọlaiya Igwe ṣe gbadura fun oludije funpo aarẹ APC leti okun nihooho ree.

Ṣugbọn oriṣiiriṣii oju ni awọn to ri fidio naa fi n wo o. Ọpọ awọn to sọrọ lo si koro oju si ohun ti ọkunrin yii ṣe. Eyi to bi wọn ninu ju ni bibọ ara ẹni sihooho ọmọluabi. Wọn ni ko ba aṣa Yoruba mu, bẹẹ ni Islaamu paapaa to loun n ṣe ko fọwọ si i. Wọn ni beeyan ba tiẹ maa gbadura nihooho ọmọluabi lati fi ẹdun ọkan rẹ han si Ọlọrun, inu ile ẹni lo yẹ ko jẹ, ki i ṣe nita gbangba.

Ṣugbọn awọn kan ni ko sohun to buru ninu ohun to ṣe, nitori oun lo ni ara rẹ.

Lara awọn to kọ ọrọ sisalẹ fidio ọhun ni horla-becee, o ni ‘oju de n ti mi ṣa. Bẹẹ lo fi ami ẹni to n sunkun si i.

Bakan naa ni ẹnikan to pera ẹ ni bukkyfashon sọ pe, ‘Nibo lawọn ọmọ ọkunrin yii wa o, nitori eyi to n ṣe yii ki i ṣe ojulasan mọ o. Ọlọrun ki i gbọ iru adura bayii, to ba wu ọ ki o ko sinu ina, ṣiọ’.

Spontaneouspearl sọ ni tiẹ pe, ‘Were pọnbele leleyii o, Ọlaiya Igwe, njẹ o mọ ohun ti o n ṣe ṣa, ṣe ori rẹ pe bayii’

Baliks_alaga sọ ni tiẹ pe, ‘Dadi, ẹ tori ile aye, ẹ ba ọrun yin jẹ, subhanalah, lori kin ni ṣa, nitori owo ṣa, ẹ ronu re o, ẹ ranti ọjọ atisun o.

_Ọmọlabakẹ sọ ni tiẹ sọ pe ‘Ṣe tori ẹ fẹẹ ko Naijiria sinu wahala lẹ ṣe n ṣe bii oloriburuku, lẹ n ṣe oṣi. Oponu agbalagba, alatẹnujẹ. Ẹ maa pada rin ihooho wọja ni, olofo, ẹlẹsin-in.

j.beautician_concept kọ ni tiẹ pe, ‘Daddy, ẹ tete diliiti fidio yii ni kiakia o, tori awọn ọmọ yin ko gbọdọ maa ri iru eleyii o, idojuti gbaa ni’.

akindeleliadi sọ ni tiẹ pe, ‘Eleyii ri i yan lara o, o si biiyan ninu,ṣe ẹ ṣiwere ni? Lori kin ni? Eleyii ki i ṣe ọna to dara lati fi atilẹyin han rara.”

topboli_creed sọ ni tiẹ pe: ”Were gidi leleyii o, ta lo ran yin ni gbogbo eleyii, awọn ọmọ yin si wa nibẹ, wọn aa maa ri i bẹ ẹ ṣe n da wahala silẹ lori oludije ti ko ni idaniloju pe oun maa wọle. Kai, eleyii ba ni lọkan jẹ’.

adeolaopeyemi3 kọ ni tiẹ pe, ‘Onidii pa poo bii burẹdi Agege, granpa to n ṣẹlẹlẹya, alatẹnujẹ oṣhi. Fun ẹyin obinrin ti ẹ n yan eleyii lale, ẹ waa gbe dadi yin ẹlẹlẹya ooo’.

Ọkan-o-jọkan ọrọ lawọn eeyan ti kọ sidii fidio naa, ṣugbọn ohun to han ninu ohun ti wọn kọ ni pe inu opọ eeyan ko dun si fidio ti ọkan ninu awọn agba oṣere tiata naa gbe sita.

 

Leave a Reply