Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn oṣiṣẹ ijọba kan ti wọn n ṣiṣẹ nileewosan ẹkọṣẹ-iṣegun Fasiti ipinlẹ Ondo, to wa lagbegbe Oke-Aro, niluu Akurẹ, ko faraare lọ sile wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, latari iya nla ti wọn jẹ lati ọwọ awọn ẹbi ọkunrin kan to ku sileewosan ọhun lọjọ naa.
Yatọ si awọn oṣiṣẹ ti wọn lu lalubami, ọpọ awọn dokita ati nọọsi ti wọn wa ni ọsibitu ọhun lasiko ti laasigbo ta a n sọrọ rẹ yii waye ni wọn fara pa yannayanna nibi ti olukuluku ti n sa asala fun ẹmi rẹ.
ALAROYE gbọ pe alaisan kan ti wọn porukọ rẹ ni Ewagwu Augustine, lo ku lọjọ naa, eyi ni awọn mọlẹbi ọkunrin ọhun fi fibinu pokọ iya fun diẹ lara awọn oṣiṣẹ ile-iwosan ọhun latari ẹsun ti wọn fi kan wọn pe iha ko-kan-mi ti wọn kọ si itọju rẹ lo ṣe okunfa bo ṣe ku laipe ọjọ.
Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun, Nọọsi ọkunrin kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Baale Emmanuel, ni iku ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta ọhun ko wa lati ọdọ awọn to jẹ oṣiṣẹ ọsibitu naa rara. O ni aigbọran ati aigba imọran oloogbe funra rẹ ati ẹbi rẹ lo ran an sọrun apapandodo.
O ni wọn ti kọkọ gbe ọkunrin naa wa si ọdọ awọn lọjọ diẹ sẹyin fun itọju lori ijamba kan to ni, ṣugbọn to kọ jalẹ nigba ti awọn n ṣeto ati gba bẹẹdi fun un ko le gba itọju to peye, to ni oun ko fẹ.
Nigba ti wọn ri i pe ọrọ aisan rẹ ti fẹẹ yiwọ lo ni awọn ẹbi rẹ tun sare gbe e pada wa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ti awọn si sa gbogbo agbara to wa ni ikawọ awọn lati tọju rẹ.
O ni gbogbo igbiyanju awọn lati fun un lẹjẹ ati abẹrẹ ti ko so eeso rere lo mu ki awọn gba awọn eeyan rẹ nimọran lati tete maa gbe e lọ sileewosan mi-in, nibi to tun ti le ri itọju daadaa lati ọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ dokita.
Nọọsi Emmanuel ni awọn fun wọn laaye lati lo ọkọ ambulansi awọn lati gbe e lọ, ṣugbọn funra wọn ni wọn kọ jalẹ, ti wọn ni awọn ni ọkọ tawọn ti awọn le lo.
Lẹyin-o-rẹyin lo ni wọn tun pada wa nigba ti ọrọ ti fẹẹ yiwọ tan, ti wọn ni awọn ti ṣetan lati lo ambulansi ijọba. Ọkunrin naa ni eto yii lawọn n ṣe lọwọ ti alaisan ọhun fi ku.
Ori oṣiṣẹ kan ti ko darukọ rẹ lo ni wọn ti kọkọ bẹrẹ akọlu wọn, ki wọn too fi abọ sori ẹni to jẹ awakọ ambulansi to fẹẹ gbe wọn. O ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ alaabo ọsibitu naa jẹ igbati lati ọwọ iyawo oloogbe, ati pe ori lo ko dokika kan yọ lọwọ wọn pẹlu.
Gbogbo akitiyan awọn ẹsọ alaabo ile-iwosan naa lati da wọn lẹkun lo ni o ja si pabo. O ni awọn ọlọpaa ati ẹsọ Amọtẹkun ni wọn pada pe lati waa gba wọn silẹ lọwọ awọn ẹbi oloogbe ọhun.
Nigba to n gbẹnu awọn alaṣẹ ọsibitu naa sọrọ, Ọgbẹni Luyi Abiọdun to jẹ Akọwe gbogbogboo ile-iwosan ọhun ni iṣẹlẹ ọhun ki i ṣe igba akọkọ tawọn ẹbi alaisan yoo maa ṣe akọlu si awọn oṣiṣẹ lẹnu iṣẹ wọn.
O ni ẹbẹ oun si ijọba ni pe ki wọn ṣeto ọlọpaa ati ẹsọ Amọtẹkun ti yoo maa daabo bo awọn sinu ayika ile-iwosan nipinlẹ Ondo.