Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti yọ ara rẹ kuro ninu awọn gomina ti Aarẹ Muhammadu Buhari fẹsun kan pe wọn n nawo epo ti wọn gba lati ọwọ ijọba apapọ ati ti ijọba ibilẹ wọn ni ina apa.
Aketi sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlatunde, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kejila yii.
Bo tilẹ jẹ pe agba agbẹjọro naa ko sọ ni pato iye owo to ri gba ninu atẹjade ọhun, ṣùgbọ́n o fidi rẹ mulẹ pe loootọ nijọba oun tẹwọ gba ida mẹtala owo ele ori epo ati iranwọ SURE-P lati asunwọn ijọba apapọ laarin ọdun 2021 si 2022.
Akeredolu ni awọn owo ọhun loun lo lati fi san diẹ lara ajẹsilẹ gbese owo–oṣu awọn oṣiṣẹ to wa nilẹ, ati fun iṣẹ akanṣe kaakiri ipinlẹ Ondo.
Aketi ni oun le fọwọ rẹ sọya pe oun na gbogbo owo ti oun ri gba lọwọ ijọba apapọ bo ṣe yẹ, bẹẹ ni oun ko fẹ ki wọn maa ka orukọ oun mọ awọn gomina to n ji owo to jẹ ti ijọba ibilẹ wọn ko.
Lara awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to ni oun fi awọn owo naa ṣe ni titi ọlọda ni Ararọmi-Alape, n’ijọba ibilẹ Ilajẹ, Ikaramu, Akunnu si Chainnage, Oke-Agbe Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, ọna tuntun ni Agadagba-Ọbọ, nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, Oke-Igbo, Ilẹ-Oluji, Akurẹ, Emure si Iporo atawọn ọna mi-in.
Aketi ni ohun ti eto ijọba toun duro le lori ni ṣiṣe iṣẹ ilu pẹlu ootọ inu, bẹẹ oun ko ṣetan tabi yẹsẹ rara lori ilana naa.