Awọn agbebọn to ji ti Kabiyesi gbe laafin l’Ondo n beere fun ọgọrun-un Miliọnu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn agbebọn to ya wọ aafin Oloṣo ti Oṣó-Àjọwá, n’ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, nibi ti wọn ti ji ori-ade ilu ọhun, Ọba Clement Jimoh Olukọtun, gbe lọ la gbọ pe wọn ti kan si awọn ẹbi kabiyesi ọhun, ti wọn si n beere fun ọgọrun-un kan Miliọnu Naira ki wọn too le tu u silẹ ninu igbekun wọn.

Ọjọ Abamẹta, Satide, iyẹn lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ti ji ọba alaye ọhun gbe sa lọ ni wọn lawọn agbebọn ṣẹṣẹ kan si awọn ẹbi rẹ, ti wọn si ni wọn gbọdọ wa owo nla ti wọn n beere fun yii wa ki awọn too le yọnda rẹ ko pada siluu.

Lati igba ti awọn agbebọn ọhun ti ya wọ aafin ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ti wọn si fipa ji Ọba Olukọtun gbe lọ lawọn ọdẹ ilu, fijilante atawọn ọdọ kan ti fọn sinu igbo lati ṣawari ọba wọn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n akitiyan wọn ko ti i so eeso rere titi di asiko yii.

Asaaju kan niluu Ajọwa Akoko, Ọgbẹni Sọji Ogedengbe, ṣalaye fun akọroyin wa lori foonu pe ọkan-o-jọkan eto adura, iṣọ-oru ati aawẹ lawọn araalu ti ṣeto rẹ ki ọba awọn le pada wale layọ ati alaafia

Leave a Reply