Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lẹyin ọjọ meje to ti wa lakata awọn ajinigbe, wọn ti tu Oloṣo ti Oṣó Ajọwa Akoko, Ọba Clement Jimoh Olukọtun, silẹ.
Ọba Olukọtun ti awọn agbebọn kan ya wọ aafin rẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ṣẹṣẹ yọnda ko maa lọ sile rẹ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkan ninu awọn ẹbi ọba alaye ọhun pe miliọnu mẹwaa Naira lawọn ajinigbe naa gba lọwọ awọn ki wọn too tu u silẹ ninu igbekun wọn.
Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe ri aduru owo bẹẹ ko jọ, o ni ko sẹyin ijọba, awọn ijoye, ara ati ọrẹ Ọba Olukọtun funra rẹ ati awọn ọmọ bibi Oṣó Ajọwa nile ati lẹyin odi.
O ni ko pẹ rara ti awọn san owo naa tan nigba tawọn ajinigbe ọhun pe awọn lati ipinlẹ Kogi ti wọn gbe Kabiyesi lọ, ti wọn si fọkan awọn balẹ pe ki awọn maa reti itusilẹ rẹ laipẹ.
Ọba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrin ọhun lo ni wọn lọọ ja si aarin Lọkọja si Kabba, nipinlẹ Kogi, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, nibi ti awọn ẹbi rẹ ti ṣeto ati gbe e pada wale.
Ileewosan kan to kọ lati darukọ rẹ fun wa lo ni awọn gbe Kabiyesi lọ, nibi to ti n gba itọju lọwọ. O ni ọba naa ko ni i pẹẹ dara pọ mọ awọn eeyan rẹ lẹyin ti ara rẹ ba ti ya daadaa.
.