Cute Abiọla pin owo-oṣu rẹ akọkọ nipo oludamọran fawọn opo ati arugbo ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gbajumọ adẹrin-in poṣonu ọmọ bibi ilu Ilọrin, to tun jẹ oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Kwara lori lori ọrọ to ba jẹ mọ iṣẹ ọna, iyẹn Special Assistant on Creative Industries nni,  Abdulgafar Ahmad Oluwatoyin, ti ọpọ eeyan mọ si Cute Abiọla, ti fi owo-osu akọkọ to gba nidii ipo oṣelu to di mu tọrẹ fun awọn opo ati arugbo nipinlẹ naa.

Lasiko ti Cute Abiọla n pin owo naa, o ni Ọlọrun lo ba oun sọrọ pe ki oun pin owo-osu oun akọkọ fun awọn alaini.

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila yii, lo safihan ibi ti adẹrin-in-poṣonu naa ti n pin owo ọhun fun awọn to ku diẹ kaato fun yii lati fi ṣe iranlọwọ fun wọn ki wọn le rọwọ ki bọ ẹnu.

Awọn opo ati arugbo to to ọgbọn ni wọn jẹ anfaani owo naa. Awọn eeyan naa ko le pa idunnu wọn mọra fun oore ti ọmọkunrin yii ṣe fun wọn. Niṣe ni ọpolọpọ wọn rọgba yi i kan, nibi to si ka awọn mi-in ninu wọn lara de, ẹkun ni wọn bu si nitori wọn ko rokan oore ojiji ti ọmọkunrin naa ṣe fun wọn.

O jọ pe bi awọn arugbo ati awọn opo yii ti n sunkun ayọ lo mu ki ori Gafar naa wu, loun naa ba bẹrẹ si i ṣomi loju.

Niṣe ni wọn n rọjo adura le ọmọkunrin to ti figba kan jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ wa yii lori, toun naa si n ṣe ami ni koṣẹkoṣẹ.

Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni ọmọkunrin yii gba iṣẹ oṣelu, to si gbe e si ori ikanni ayelujara rẹ. Ko pẹ sigba naa lo kọwe fipo silẹ nileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ wa to ti n ṣiṣẹ, to si dupẹ lọwọ gbogbo awọn ọga ati alabaaṣiṣẹpọ rẹ fun anfaani ti wọn fun un lati sin ilẹ Naijiria latara ileeṣẹ yii.

Leave a Reply