Monisọla Saka
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC marun-un ni wọn ti faye silẹ bayii nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun yii, lori omi Gbaramatu si Warri, nipinlẹ Delta. Nigba tawọn kan ba iṣẹlẹ naa lọ, awọn mi-in wa nileewosan ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Ọkọ oju omi to danu yii ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ atawọn alatilẹyin wọn ti wọn n dari bọ lati ibi ipolongo ibo gomina ẹgbẹ wọn, eyi to waye niluu Okerenkoko ati Ugborodo, nijọba ibilẹ Guusu Warri wọ.
Ọkọ oju omi yii ni wọn lo lari mọ eyi to ko awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, eyi lo si yọri si bi ọkọ naa ṣe gbokiti, to doju de. Loju-ẹsẹ nibẹ lawọn eeyan meji kan ti gbẹmi-in mi, tawọn mẹta ri sisalẹ omi. Awọn meje ti wọn ribi doola ti wa l’ ọsibitu, nibi ti wọn ti n gba itọju latari ọgbẹ ti wọn gba nibi iṣẹlẹ naa.
Oludije dupo gomina ipinlẹ Delta, to tun jẹ igbakeji olori ileegbimọ aṣofin agba nilẹ wa, Sẹnetọ Ovie Ọmọ-Agege, banujẹ gidigidi lori iṣẹlẹ naa, o loun to ba ni lẹru, to si ṣẹlẹ lai ro tẹlẹ ni, o waa gbadura pe ki Ọlọrun fun ẹmi awọn eeyan naa nisinmi.
Ninu atẹjade ti Ima Niboro, ti i ṣe adari ikọ onipolongo ibo gomina ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Delta fi sita L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, lo ti sọ pe, “Iṣẹlẹ ibanujẹ yii ba wa lẹru, o ba wa lojiji, o si ka wa laya, adura wa fawọn oloogbe atawọn mọlẹbi wọn ni pe ki Ọlọrun wa pẹlu wọn, ko si fun wọn ni isinmi. Inu ọfọ nla lẹgbẹ wa wa bayii.
“A n ṣiṣẹ lọwọ bayii pẹlu awọn tọrọ kan atawọn araalu lati wa oku awọn to ri sinu omi ni awari. Bẹẹ la tun n lakaka lati kan si mọlẹbi awọn ti wọn padanu ẹmi wọn, kawọn ti wọn wa lọsibitu si gba iwosan to peye.
Nitori ati ṣapọnle awọn ti wọn ti ku, awọn ti wọn sọnu atawọn ti wọn ṣeṣe yii, a ti fẹnu ko lati dawọ ipolongo ibo wa duro fungba diẹ na. Awọn igbimọ eleto ipolongo yoo sọ igbesẹ to ba kan laipẹ ọjọ. Lẹẹkan si i, a ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi oloogbe, a si gbadura pe ki Ọlọrun tu wọn ninu”.