Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ti tanmọlẹ si wahala to n lọ lọwọ laarin ijọba tuntun l’Ọṣun, labẹ Gomina Ademọla Adeleke, ati ijọba ana labẹ Gomina Adegboyega Oyetọla.
Lọsẹ to kọja ni igbimọ kan ti Adeleke gbe kalẹ lati ṣayẹwo awọn dukia ijọba sọ pe Oyetọla ati gbogbo awọn ti wọn ba a ṣiṣẹ ni wọn gbe mọto ayọkẹlẹ to jẹ tijọba lọ, wọn ni, koda, iyawo gomina naa tun gbe lara awọn mọto naa.
Igbimọ yii waa paṣẹ pe ki wọn da gbogbo awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa pada kiakia ko too di pe wọn yoo maa fi agbara ofin gba a lọwọ wọn kaakiri.
Latigba naa ni ariyanjiyan ti bẹrẹ lori aṣẹ yii, bi awọn ọmọ Oyetọla ṣe n sọ pe ofin faaye gba gomina atawọn kọọkan lati gbe awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa lọ, niwọn igba ti akọsilẹ to yẹ ba ti wa lori wọn, ni awọn ọmọ Adeleke n sọ pe ko si ofin to faaye iru ẹ silẹ fun wọn.
Ṣugbọn Olori awọn aṣofin, Owoẹyẹ, ti kan oju abẹ ọrọ naa nikoo ninu ijokoo ile l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe ofin faaye gba awọn igbesẹ ti Oyetọla gbe.
O ni gẹgẹ bo ṣe wa ninu abadofin to ni i ṣe pẹlu awọn to di ipo mu, iyẹn, State Public Office Holders (Payment of pension and severance packages) ti ọdun 2018, to si di ofin lọdun 2019, gomina to ba kuro lori aleefa laṣẹ lati gbe awọn ọkọ ijọba to lo lọ.
Lati le ṣalaye ọrọ yii ni kikun fun awọn ijọba tuntun, Owoẹyẹ ranṣẹ pe Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun, Teslim Igbalaye, ati Olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Kassim Akinlẹyẹ, pe ki wọn farahan niwaju awọn aṣofin.
O ni ọpọlọpọ nnkan ni asọyepọ le yanju lai ta epo si aṣọ aala ẹnikẹni.