Awọn agbanipa dana sun oṣiṣẹ banki atiyawo ẹ mọle lẹyin ti wọn pa wọn tan, l’Abẹokuta
Faith Adebọla, Ogun
Ibi ijọsin adura alaja ọdun, eyi tọpọ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni maa n lọọ gba lalẹ ọjọ to kẹyin ninu ọdun si idaji ọjọ ki-in-ni ọdun tuntun ni tọkọ-taya Kẹhinde Fatinoye ati ọmọ wọn ọkunrin kan ti n dari bọ lafẹmọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ ki-in-ni, oṣu Ki-in-ni, ọdun 2023 yii. Ko pẹ ti wọn wọle tan lawọn afurasi agbanipa kan wọle tọ wọn, wọn yinbọn pa tọkọ-tiyawo naa, lẹyin ti wọn pa wọn tan ni wọn dana sun oku wọn, wọn si ji ọmọ wọn ati ọmọọdọ wọn kan gbe lọ.
Iṣẹlẹ ibanujẹ yii waye laduugbo GRA Ibara, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.
Banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria, ẹka ti Abẹokuta, ni baale ile yii ti n ṣiṣẹ, akọwe agba si ni iyawo rẹ ni fasiti ẹkọ nipa iṣẹ agbẹ, iyẹn Federal University of Agriculture, FUNAAB, l’Abẹokuta.
Alaroye gbọ pe niṣe lawọn apaayan ẹda naa lugọ pamọ de awọn tọkọ-taya yii, tori ko si mọto kankan to tẹle wọn wọle lẹyin ti wọn dari de lati ileejọsin ti wọn lọ, gẹgẹ bawọn aladuugbo wọn ṣe wi, ko si sẹni to gburoo ibọn lasiko tiṣẹlẹ naa fi waye, afi bi ina ṣe n jo bulabula lojiji nile ọhun, nigba tawọn eeyan yoo si fi rọ debẹ, oku awọn mejeeji ni wọn ba. Awọn to ṣiṣẹẹbi ọhun ti fẹsẹ fẹ ẹ, wọn si ti ko awọn meji lọ.
Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, ko ti i sẹni to gburoo awọn ti wọn ji gbe ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
O ni: “Loootọ niṣẹlẹ naa waye, a si ti bẹrẹ iwadii lẹyẹ-o-sọka lori ẹ. A ti ri ẹni kan mu nipa iṣẹlẹ ọhun. Wọn pa ọkunrin kan ati iyawo rẹ, a o si ti i ri ọmọ wọn ti wọn ji gbe lọ.
“Aajin oru ọjọ ki-in-ni, oṣu Ki-in-ni, ọdun tuntun yii, niwadii fihan pe iṣẹlẹ naa waye. Gbogbo ẹri to wa nikaawọ wa fihan pe awọn agbanipa ni wọn ṣiṣẹ naa. A o ti i mọ idi ti wọn fi ṣe e tabi ẹni to bẹ wọn lọwẹ iṣẹ oro ti wọn jẹ, ṣugbọn a o ni i duro lori iwadii titi ta a fi maa tuṣu ọrọ yii desalẹ ikoko lati mọ okodoro ohun to fa iṣẹlẹ laabi yii.”
Bẹẹ ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ.