Peter Obi da Tinubu loun: Mo le lahun loootọ, ṣugbọn ọwọ mi ko kun fun iwa ibajẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu Labour ninu eto idibo gbogbogboo ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, osu Keji, ọdun ta a wa yii, Peter Obi, ti fun Bọla Hammed Tinubu lesi ọrọ rẹ lasiko to gbe eto ìpolongo rẹ wa si ilu Akurẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọjá.

Obi ni oun gba pe oun lahun loootọ ni ibamu pẹlu ẹsun tí oludije sipo arẹ lẹgbẹ òṣèlú APC náà fi kan oun, ṣugbọn inu oun dun pupọ pe ọwọ oun ko kun fún ìwà ibajẹ.

O ni oun rọ Tinubu ko lọọ wo akọsilẹ oun dáadáa, nitori pe ahun tí oun ni títí ree ti oun fi raaye ko owo to to bíi miliọnu mẹrindinlọgọjọ dọla jọ fáwọn eeyan ipinle oun láàárín ọdun mẹjọ pere ti oun fi wa lori aleefa gẹ́gẹ́ bíi gomina ipinlẹ Anambra.

Ó ní oun ko owo nla yìí jọ lai fi ti ipo ti ko níláárí tí eto ọrọ aje ipinlẹ náà wá lásìkò ọhun ṣe, lai jẹ banki tabi awọn kọngila kankan lowo iṣẹ.

O ni ko gba ẹnu Tinubu rara lati maa sọko ọrọ si oun nitori ipilẹ oun fúnra rẹ ki i ṣe ohun tí eeyan gidi kan le fi yangan larin àwọn ọmọlúwàbí.

Oludije sipo aarẹ ọhun ni oun le fọwọ́ rẹ sọya pe ko si ẹbọ olookan tó wa lẹru òun ati Ahmed Dati to jẹ igbakeji oun, yatọ si awọn èèyàn kan ti wọn n bẹru ati sọ ojulowo orúkọ ti wọn n jẹ pẹlu ileewe tí wọn làwọn ti kàwé fáwọn araalu.

Obi waa ṣeleri ati mu igba ọtun ba awọn oníṣòwò kéékèèké lẹyin to ba di aarẹ tan,  o ni oun ti ṣetan lati wa ọna àbáyọ oju-ẹsẹ si ọrọ àìsí ina ọba, eyi to n ba awọn eeyan ẹkùn idibo Guusu ipinlẹ Ondo fínra láti ọdun pipẹ wá.

O rọ àwọn oludibo kí wọn sọra fun ọrọ ẹlẹyamẹya, kí wọn ma si ṣe tẹti si ariwo ’emi lọ kan’ tawọn oloṣelu kan n pa kiri, ó ní ohun to yẹ ko jẹ wọn logun ju lọ lásìkò yii ni bi Naijiria yoo ṣe padabọ sipo.

Leave a Reply