Stephen Ajagbe, Ilọrin
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Yakubu Danladi-Salihu, ti fi da awọn araalu loju pe ijọba yoo ṣe ọna Kaiama si Baruten tijọba ana lawọn na biliọnu kan naira si lai si ayipada rere kankan.
Ọna ọhun, bẹrẹ lati Kaiama si Kpura wọ Kosubosu nijọba ibilẹ Baruten lo ti bajẹ patapata to si mu iṣoro ba awọn arinrinajo to n gba oju ọna naa kọja.
Danladi, sọrọ ọhun ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki rẹ feto iroyin, Ibrahim Sheriff gbe sita, lasiko to ko awọn ikọ kan sodi lati lọọ yẹ ọna naa wo laarin ọsẹ to kọja lo sọrọ idaniloju naa fun Emir ilu Kaiama, Sheu Omar Muazu, laafinẹ rẹ.
O ni o jẹ ohun to bani lọkan jẹ pe pẹlu ipa ti agbegbe naa n ko ninu idagbasoke ọrọ-aje Kwara awọn ijọba to kọja ko ṣe atunṣe oju ọna naa.
O ni ile aṣofin naa ṣi n tẹsiwaju ninu iwadii lori biliọnu kan le igba naira, N1.2b, tijọba ana lawọn na fun atunṣe ọna naa.
Ninu esi ti wọn ni ọba ilu Kaiama fun olori aṣofin naa, o ni inira nla ni ọna naa n mu ba araalu, paapaa julọ iṣẹlẹ ijinigbe wọpọ lagbegbe naa.
Awọn aṣofin naa pẹlu kọmiṣana fun iṣẹ-ode ati eto irina, Rotimi Iliasu tun ṣe abẹwo si awọn afara meji to so Kaiama ati Kemanji pọ eyi to ti fẹẹ da wo. Iliasu ni ijọba yoo wa nnkan ṣe si i ni kiakia.