Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari bi ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ ninu ibo gomina ipinlẹ Ọṣun ṣe sọ pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke ko gbọdọ jo ‘Buga’ mọ, ti wọn ni Alhaji Gboyega Oyetọla lo jawe olubori lo mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP fọn sita lawọn ilu kọọkan lọjọ Abamẹta, Satide, lati fi aidunnu wọn han si idajọ naa.
Awọn oju-ọna kọọkan ni ilu Oṣogbo, Ileṣa, Ikirun ati Ẹdẹ lawọn eeyan ti inu n bi ọhun gbegi di, ti wọn ko si jẹ ki awọn onimọto ati ọlọkada raaye kọja.
Alubami ni wọn n na ọlọkada to ba fẹẹ ṣagidi kọja laarin wọn, ti wọn si gbe oriṣiiriṣii akọle lọwọ pẹlu orin lẹnu wọn pe awọn ko ni i laju silẹ ki kootu gba ọna ẹburu gbe kinni ọhun fun Oyetọla.
Ọpọ awọn arinrin-ajo loju ọna Oṣogbo si Ikirun ati Gbọngan si Oṣogbo ni wọn daamu pupọ nitori ko si ọkọ ti yoo gbe wọn, ojukan naa si lawọn ti wọn ti wọ mọto lati gareeji wa fun ọpọlọpọ wakati.
Pupọ awọn ọlọja ni wọn ko tilẹ ṣi ṣọọbu nitori ibẹru ki awọn tọọgi ti wọn darapọ mọ awọn olufẹhonu han naa ma baa kọ lu wọn.
Ni agbegbe Ìgbọ̀nà, niluu Oṣogbo, awọn ti wọn jẹ ọmọ igbimọ to n ṣakoso igbokegbodo ọkọ ti Adeleke ṣẹṣẹ yan nipinlẹ Ọṣun da ọkọ kọmiṣanna ọlọpaa, Kehinde Longẹ duro, ti wọn ko jẹ ko kọja.
Ṣugbọn awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti wọn ba kọmiṣanna kọwọrin ni wọn lọọ ko awọn nnkan ti wọn ko di oju-ọna ọhun kuro.
Niluu Ileṣa, wọn ko jẹ ki irinkerindo ọkọ wa ni orita olobiripo ilu naa, to si jẹ pe ẹsẹ lawọn araalu fi n rin lọ sibi ti wọn n lọ.
Alaroye gbọ pe bi awọn kan ṣe n fẹhonu han lawọn janduku kan n lọ kaakiri lati ba awọn ile-ẹgbẹ oṣelu APC jẹ, bẹẹ ni wọn si n ya patako ipolongo ibo to ba ti jẹ ti APC.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe alaafia ti n jọba pada nitori awọn ti ko ọpọlọpọ awọn ọlọpaa lọ sawọn ilu ti wọn ti gbegi dina naa.