Faith Adebọla
Ile-alaja rẹpẹtẹ kan ti wọn n kọ lọwọ niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ti wo lulẹ ni nnkan bii aago mejila ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko tawọn oṣiṣẹ atawọn agbaṣẹṣe n da kọnkere ọkan ninu awọn aja ile naa lọwọ, ọpọ eeyan ni ile naa wo lu mọlẹ, wọn o si ti i ri ẹnikẹni yọ jade labẹ ẹbiti naa titi di ba a ṣe n sọ yii.
Iṣẹlẹ yii waye lagbegbe Gwarinpa, niluu Abuja, l’Opopona kan ti wọn n pe ni 4th Avenue, nidojukọ ileetaja igbalode C-Bricks and More.
Ninu fidio kan ti ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ gbe sori ẹrọ agbọrọkaye tuita (twitter) rẹ, o ṣafihan bawọn oṣiṣẹ ti ori ko yọ layiika awoku ile naa ṣe n sa kijokijo, ti ọpọ si n kawọ mọri, ti wọn n sọ pe ọpọ awọn oṣiṣẹ ni wọn ṣi wa labẹ awoku naa, wọn lawọn n gburoo igbe, ‘ẹ ran wa lọwọ, ẹ ṣaanu wa o’ tawọn kan lara wọn n pa.
Bẹẹ ni fidio naa ṣafihan ọparun ati irin jangan-jangan ti wọn fi gbe kọnkere duro lasiko ti wọn n kun dẹkinni ile naa, amọ ti gbogbo ẹ ti wo lulẹ bẹẹrẹ.
Alaroye gbọ pe awọn to n ṣiṣẹ lọwọ nibi ile to da lulẹ ọhun maa n ju aadọta lọ loojọ.
A gbọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti ijọba apapọ, National Emergency Management Agency (NEMA) ti de ibi iṣẹlẹ ọhun, wọn si ti n ṣe aayan lati ko ẹbiti kuro lori awọn to ha sabẹ awoku naa.