Faith Adebọla
Ireti awọn araalu lati mọ pato ọjọ ti gbedeke nina owo Naira atijọ yoo kasẹ nilẹ, ati ibi ti idajọ yoo duro le lori ẹjọ to wa ni kootu ko wa si imuṣẹ, niṣe ni ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa sun igbẹjọ siwaju, wọn lo di Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii, iyẹn ọsẹ to n bọ, kawọn too bẹrẹ igbẹjọ lori ẹjọ naa.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, ni Adajọ John Okoro, to lewaju awọn adajọ meje ti kootu to ga ju lọ ọhun ti sọ pe igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹjọ tawọn gomina ipinlẹ mẹta kan gbe wa siwaju awọn lati ta ko gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii, ti banki apapọ ilẹ wa kede pe nina awọn owo Naira atijọ, iyẹn igba Naira (N200), ẹẹdẹgbẹta Naira (N500) ati ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) yoo dopin, tori wọn ti paarọ awọ owo wọnyi, wọn ti foju owo tuntun naa lede.
Awọn gomina ipinlẹ mẹta ti wọn pẹjọ ta ko ikede ọhun ni Zamfara, ipinlẹ Kaduna ati ipinlẹ Kogi. Ọjọ kẹjọ, oṣu Keji yii, ni wọn pẹjọ nipasẹ agbejọro wọn, Amofin agba Abdulhakeem Mustapha, ẹni to ṣoju fawọn kọmiṣanna feto idajọ lawọn ipinlẹ mẹtẹẹta lorukọ awọn gomina wọn. Minisita feto idajọ, Amofin agba Abubakar Malami, ni olujẹjọ, lorukọ ijọba apapọ.
Lẹyẹ-o-sọka ni ile-ẹjọ to lewaju awọn kootu gbogbo nilẹ wa ti paṣẹ lọjọ naa pe ki banki apapọ ati ijọba ṣi mọwọ duro na lori gbedeke ọjọ kẹwaa, wọn ni kawọn eeyan maa na owo mejeeji, iyẹn owo atijọ ati owo tuntun, niṣo titi ti igbẹjọ yoo fi waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii.
Aṣẹ yii lo tubọ mu kara dẹ awọn eeyan ti wọn ti ko ọkan soke lori ọwọngogo owo tuntun ati kara-kata to dẹnu kọlẹ latari gbedeke ọhun, ki wọn too so o rọ. Amọ bo ṣe ku ọjọ diẹ ki ọjọ kẹẹẹdogun ti ireti wa pe igbẹjọ yoo bẹrẹ, aifararọ, aroye, iwọde, ifẹhonu han ati ipenija lo tun gbalu kan lakọtun. Eyi ko ṣẹyin bawọn banki kan, awọn ileepo, awọn oniṣowo, awọn onimọto, to fi mọ ile-ẹjọ nilẹ yii ko ṣe gba owo atijọ naa lọwọ awọn araalu, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe gbogbo wọn, wọn lawọn o fẹ, owo tuntun ni wọn n gba tabi ki wọn fowo ṣọwọ lori ẹrọ si ara wọn, eyi ti wọn n pe ni tiransifaa.
Awọn ọga agba banki kan ṣaroye pe, bo tilẹ jẹ pe loootọ lawọn gbọ nipa aṣẹ ile-ẹjọ ti gbogbo ẹjọ n pẹkun si naa, sibẹ aṣẹ yii o ti i le rẹsẹ walẹ lọdọ tawọn tori banki apapọ ko ti i kọwe sawọn nipa ẹ, ila o si le ga ju onire lọ, banki apapọ lo gbọdọ sọ fawọn boya kawọn ṣi maa gba owo atijọ naa niṣo, nigba ti banki naa ko si ti wi nnkan kan, eti lobinrin fi n gbohun oro lawọn fi aṣẹ ti kootu giga ju lọ naa ṣe. Lara awọn ọga banki naa tun sọ pe owo tuntun o si lọwọ awọn mọ, eyi ti wọn ko fawọn ti tan, eyi ni ko jẹ kawọn ri owo naa fi ṣe ipaarọ faraalu.
Gbogbo ipọnju tawọn eeyan n doju kọ yii lo mu kawọn iwọde bẹrẹ si i waye kaakiri awọn ipinlẹ kan, amọ lọtẹ yii, awọn ẹka ileeṣẹ banki apapọ ni ọpọ awọn oluwọde ko rẹi-rẹi wọn lọ, wọn ni ki wọn ṣẹ owo atijọ ọwọ awọn si tuntun, ki wọn si rọju gbedeke yii, tori inira ti eto ipaarọ owo yii mu wọ ti fẹẹ sun awọn kangiri. Eyi waye nipinlẹ Edo, Delta, Ogun, Ondo, Ọyọ ati Rivers.
Amọ, Yooba bọ, wọn ni ba a ti ṣe la a wi, ẹnikan ki i yan ana ẹ lodi. Ọga agba banki Central Bank of Nigeria, CBN, Godwin Emefiele, tilẹkun mọri ṣepade pẹlu Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, nileeṣẹ Aarẹ, l’Abuja. Lọjọ keji, Emefiele sọrọ nipa awuyewuye naa pe ko sidii kan lati fi ọjọ kun gbedeke ọjọ kẹwaa, oṣu Keji, tawọn ti mu gẹgẹ bii ọjọ ti nina owo atijọ gbọdọ dopin. O ni lọdọ tawọn o, ọjọ naa ni awọn owo atijọ ti di kọndẹ lọja. Bakan naa lo di ẹbi owo tuntun ti ko si nita ru awọn olokoowo ẹrọ POS atawọn oloṣelu kan, o lawọn ni wọn n ra owo tuntun labẹnu, ti wọn si fi n ṣowo pẹlu ere gọbọi lati ni araalu lara. Niṣe lọrọ rẹ yii si tun ko ipaya bawọn eeyan ti owo atijọ naa ṣi wa lọwọ wọn, ti wọn n reti ohun tile-ẹjọ yoo sọ lọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun. Wọn ni bi ifa ile-ẹjọ giga ju lọ ba fọre, ṣugbọn ti ti banki apapọ ko fọrẹ, ironu di meji fun a-bomi-sẹnu-fẹna niyẹn, ina o gbọdọ ku, omi o si gbọdọ jo danu.
Ṣa, lọjọ Wẹsidee yii, Agbẹjọro olupẹjọ, Mustapha pe akiyesi ile-ẹjọ giga ju lọ sawọn awuyewuye ti ọrọ yii ti da silẹ nigboro. O lawọn ti kọwe ẹsun ta ko gomina banki agba ilẹ wa, Godwin Emefiele, tori boun atawọn banki abẹ rẹ ṣe kuna lati tẹle aṣẹ ile-ejọ giga ju lọ naa, ti wọn n kọ owo atijọ sawọn eeyan lọwọ, o ni iwa arufin ati ọyaju niyẹn jẹ si ile-ẹjọ giga ju lọ, tori ẹ, awọn fẹ ki wọn kọ ọ lọgbọn, ko lọọ fẹnu fẹra bii abẹbẹ lahaamọ, tori ila o gbọdọ ga ju oloko lọ.
Wọn tun ni awọn rọ kootu olubori naa lati tun aṣẹ rẹ ọjọsi pa, niwọn igba ti igbẹjọ to yẹ ko waye lọjọ kẹẹẹdogun ọhun ko tun bẹrẹ mọ, ki wọn kede pe kawọn eeyan ṣi maa na owo mejeeji niṣo.
Bakan naa ni wọn fi to ile-ẹjọ naa leti pe awọn ipinlẹ mẹta ni wọn pẹjọ tẹlẹ, amọ ẹjọ naa ti fẹju kankan o, awọn ipinlẹ mi-in ti kọwe pe ki wọn forukọ awọn kun olupẹjọ, wọn ni lori ọrọ to dele yii, arun to n ṣe ogoji lo n ṣọọdunrun ni, ohun to n ṣe Abọyade, gbogbo ọlọya lo n ṣe ni, awọn o si fi ti oṣelu ṣe rara. Awọn ipinlẹ naa ni Katsina, Eko, Cross-River, Ogun, Ekiti ati Sokoto, bo tilẹ jẹ pe ninu gbogbo awọn ipinlẹ wọnyi, Sokoto nikan ni ẹgbẹ oṣelu rẹ yatọ, ti wọn jẹ Peoples Democratic Party (PDP), awọn yooku, ati ipinlẹ to pẹjọ, ati ijọba apapọ ti wọn pe lẹjọ, All Progressives Congress (APC), ni wọn.
Nigba ti Onidaajọ John Okoro maa gbe ipinnu igbimọ onidaajọ naa kalẹ o ni igbẹjọ ko ni i le bẹrẹ lọjọ naa, ọjọ kejilelogun, lawọn maa raaye tẹti si atotonu ati awijare olupẹjọ ati olujẹjọ.
Ni ti ọrọ awọn ipinlẹ tawọn naa fẹẹ dara pọ mọ olupẹjọ, wọn gba wọn wọle, wọn si ki wọn kaabọ.
Lori ẹbẹ pe ki wọn kede ọjọ mi-in gẹgẹ bii gbedeke, wọn ni ko sidii lati ṣe bẹẹ, tori awọn ti sọ tẹlẹ pe ki wọn jẹ kowo tuntun ati tatijọ ṣi wa nita, kawọn eeyan maa na wọn titi ti igbẹjọ yoo fi bẹrẹ, igbẹjọ o si ti i bẹrẹ, awọn o nilo lati ṣe awitunwi kankan lori iyẹn.
Ni ti bi wọn ṣe fẹsun kan Emefiele atawọn banki ti wọn n kọ owo sawọn araalu lọwọ, wọn ni iwe ẹsun naa ko ṣoju ṣaara to, wọn ni wọn gbọdọ pese ẹri lati fihan pe ẹbi Emefiele ni, ki wọn si fi ibi to ti tapa saṣẹ tawọn pa han ni pato, ki wọn kọwe naa daadaa, igba yẹn lawọn too le ṣiṣẹ lodi si i.
Ibi yii ni ẹjọ naa de duro di ba a ṣe n sọ yii. Ireti awọn eeyan ni lati mọ bi igbẹjọ yoo ṣe lọ si lọsẹ to n bọ. Bakan naa si ni wọn reti pe ki laasigbo lori ọrọ owo atijọ ati tuntun yii rọju, lati mu ara tu araalu atawọn ọlọja.