Wọn ju tiṣa sẹwọn gbere, ọmọ ọdun mẹfa lo fipa ba laṣepọ

Monisọla Saka

Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun yii, ni ile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, ju ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji  kan, Chukwu Ndubuisi, sẹwọn gbere, nitori ọmọ ọdun mẹfa to jẹ ọmọ ileewe ‘Mind Builders Nursery and Primary School’, to wa lagbegbe Ọmọle Phase 2, Ikẹja, nipinlẹ Eko, to ba laṣepọ nibi to ti n ṣiṣẹ olukọ.

Onidaajọ Sedoten Ogunsanya, ran Ndubuisi ti i ṣe olukọ alaabọ iṣẹ (part time teacher), to n kọ awọn ọmọ ni ẹkọ nipa iṣẹ ọna (Art), nileewe naa lẹwọn, lẹyin to ni o jẹbi ẹsun ifipa ba ọmọ kekere lajọṣepọ ti ijọba fi kan an.

Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2016, ni wọn ni iṣẹlẹ to tu aṣiri ọrọ naa waye. Nigba to di ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun 2016, ni wọn wọ Ọgbẹni Ndubisi lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Ogudu, nipinlẹ Eko, ṣugbọn o loun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Majisireeti ọhun, Onidaajọ Olufunkẹ Sule-Amzat, waa faaye beeli ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100,000), silẹ fun un pẹlu awọn oniduuro meji ti wọn jẹ ọmọ iya ẹ gangan, ti wọn si gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ.

Lẹyin ti ileeṣẹ to n gba ile-ẹjọ nimọran nipinlẹ naa, (DPP), fun wọn nimọran lori ọrọ yii, wọn tun ọdaran naa gbe, wọn si taari ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ giga ilu Ikẹja. Bo tilẹ jẹ pe ọdaran yii tun sọ pe oun ko jẹbi. Lasiko to n ka idajọ ẹ, Onidaajọ Ogunsanya sọ pe ko si ani-ani ninu awọn ẹri to wa niwaju oun yii, gbogbo ẹri yii lo ta ko olujẹjọ gẹgẹ bi wọn ṣe wi.

Adajọ ni igba akọkọ ti ọmọdebinrin ti wọn n fipa ba laṣepọ yii maa ṣalaye ọrọ naa fun mama ẹ ni ọjọ ti iya ẹ n ba a sọrọ ọmọbinrin ọmọ ọdun meje kan ti wọn pa lẹyin ti wọn fipa ba a lo pọ tan, ti ọrọ naa si gba gbogbo ilu kan.

O ni ọrọ yii lo mu ki ọmọ yii sọrọ wuyẹwuyẹ si mama ẹ leti pe oun fẹẹ sọ kinni kan fun un, nigba tawọn mejeeji jọ yẹra sita lọmọ naa sọ gbogbo nnkan to n pa mọra fun mama ẹ, lẹyin naa lo bẹ iya ẹ pe ko ma sọ fun baba oun ati ẹgbọn oun to jẹ ọkunrin.

Ile-ẹjọ ni bi mama ọmọ yii ṣe ṣalaye ọrọ naa fun baba ẹ ni wọn gbera lọ sileewe ọmọ yii, ṣugbọn ti olukọ to n kọ wọn ni iṣẹ ọna yii ko si nibẹ lọjọ naa.

O ni lati ileewe ọhun lawọn obi ọmọ yii ti lọọ fẹjọ ọrọ naa sun awọn agbofinro ni teṣan ọlọpaa Ọmọle. Loju-ẹsẹ ni wọn bẹrẹ iwadii, ile iwosan ijọba alabọọde, Ikosi Health Centre, ni wọn ti kọkọ lọọ ṣayẹwo fọmọ naa, ti wọn ti ri i pe loootọ ni wọn ba a laṣepọ.

Adajọ sọ siwaju pe, ẹjọ ọrọ yii lawọn ajọ to n ri si ifipa ba ni lo pọ ati lilo ọmọ nilokulo Domestic and Sexual Violence Agency (DSVA), tẹsẹ bọ, tawọn naa bẹrẹ iwadii.

O ni nigba tọmọdebinrin yẹn n sọ bọrọ ṣe ri fun kootu, o ni, “olukọ yẹn sọ pe ki n bọ aṣọ ileewe mi, lẹyin naa lo fi idi tiẹ sinu idi mi, nigba mi-in, o maa pe mi wọ inu awọn yara ikẹkọọ imọ art yii (Art room), to ba ti gbe mi sori tebu, to yẹ pata mi si ẹgbẹ kan, wọn aa tun fi kinni wọn sinu kinni temi”. O ni pepa fẹlẹfẹlẹ (tissue paper), lo fi maa n nu gbogbo ara oun to ba ti ṣetan.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun duro lori esi ayẹwo ti wọn ṣe fọmọ naa nileewosan Mirabel Centre, eyi to fihan pe nnkan tẹẹrẹ to duro gẹgẹ bii ibale loju ara obinrin ọmọ yẹn ti faya. Eleyii atawọn nnkan mi-in ni wọn lo fihan pe loootọ ni wọn ba ọmọ yẹn sun pẹlu ipa.

Lẹyin gbogbo iwadii ati ẹri ti wọn ko siwaju ile-ẹjọ, Onidaajọ Ogunsanya ni ọdaran naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, o si ran an ni ẹwọn gbere.

Leave a Reply