Nitori airowo gba ni banki, awọn araalu fẹhonu han l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn eeyan kan ni wọn tu jade niluu Ondo laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, lati fẹhonu han lori ọrọ ọwọngogo Naira to ṣi n tẹsiwaju.

Ibudokọ Akurẹ, to wa niluu Ondo, eyi tawọn eeyan mọ si Akurẹ Garaaji, lawọn to n binu ọhun ti bẹrẹ iwọde wọn, leyii to fa sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ lagbegbe naa fun bii ọpọlọpọ wakati.

Ko fi bẹẹ si wahala rara titi tawọn olufẹhonu han naa fi kọja lagbegbe Agbogboòkè, pẹlu bi ohun gbogbo ṣe n lọ ni alaafia lai si iyọnu tabi rogbodiyan kankan.

Ni kete ti wọn gbe ifẹhonu wọn de adugbo Yaba, iyẹn nitosi ibi ti Guarantee Trust Bank (GTB), wa lawọn ọmọ ita kan ba wọn da si i pẹlu bi wọn ṣe bẹrẹ si i sun taya ọkọ lagbegbe ọhun, leyii to ko ipaya nla ba awọn eeyan.

Kiakia lawọn banki gbogbo to wa lagbegbe naa ti kogba wọle, ti wọn si sare ti geeti wọn mọ awọn onibaara wọn sita (ṣe agbegbe yii ni pupọ awọn ile-ifowopamọ to wa niluu Ondo wọpọ si ju lọ latari ẹka olu ileesẹ awọn ọlọpaa, Omimọdẹ, to wa nibẹ).

Awọn ọlọpaa naa ko si jáfara ti wọn fi gbe ọkọ akọtami wọn jade si itosi ẹnu ọna teṣan wọn boya ọrọ naa yoo fẹẹ ju bi wọn ti ro lọ.

Ilẹkun gbogbo awọn banki ọhun lo ṣi wa ni titi pa nigba ta a ṣabẹwo si agbegbe naa ni nnkan bii aago mewaa aarọ kọja diẹ, ko si si eyi to gbiyanju lati tun pada ṣiṣẹ mọ titi ta a fi kuro nibẹ ni nnkan bii aago mejila ọsan ku diẹ.

Ọkan lara awọn onibaara GTB to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni ko si wahala nibi ti awọn to si, obinrin to kọ lati darukọ ara rẹ ọhun ni ṣe lawọn to lọwọọwọ sibi ẹrọ ATM tawọn ti fẹẹ gba owo, ti ẹrọ naa ko si ja awọn eeyan kulẹ rara, ti o n pọwo jade.

O ni oun ri awọn ti wọn ri ẹgbẹrun mẹwaa Naira gba dipo ẹgbẹrun marun-un ti wọn n fun awọn eeyan tẹlẹ.

Eto ọhun lo ni o n tẹsiwaju ni gbogbo igba ti ifẹhonu han fi n waye lagbegbe naa, o ni rogbodiyan to fẹẹ bẹ silẹ nibi tawọn janduku ti wọn ba wọn da si i ti n sun taya laarin titi lo ṣokunfa bi wọn ṣe da owo ti wọn n san fun awọn duro.

Ọgọọrọ awọn onibaara la ri ti wọn si to sinu oorun niwaju awọn banki bii, ECO, Stanbic, FCMB, Zenith ati GTB nigba ti ko si ẹnikẹni niwaju First banki, UBA ati Acces.

Leave a Reply