Ẹ wo Fatima to n ba awọn afẹmiṣofo, ajinigbe ra ibọn ati ọta

Faith Adebọla

Beeyan ba kọkọ pade obinrin ẹni ọgbọn ọdun ti wọn porukọ ẹ ni Fatima Sani yii, tọhun yoo ro pe ẹni alaafia ni pẹlu bo ṣe rẹwa, to si tun saaba maa n lo hijaabu tawọn ẹlẹsin Musulumi n wọ, amọ lopin ọsẹ yii laṣiiri ẹ tu pe timutinu kẹgbin da sinu ẹda kan bayii ni, wọn loun lo maa n dibọn ba awọn afẹmiṣofo, ajinigbe agbebọn ra nnkan ija bii ibọn, ọta ibọn, atawọn nnkan ija oloro mi-in tawọn ẹniibi ọhun fi ṣe araalu ni ṣuta fun wọn.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keji yii, ni wọn foju afurasi ọdaran naa hande lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, to wa niluu Gusau.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, SP Mohammed Shehu, fi lede, o ni ijọba ibilẹ Kaura Namoda, lafurasi naa n gbe, o si ti pẹ tawọn eeyan ti n fura si i, ṣugbọn ko sẹni to ka iṣẹẹbi to n ṣe naa mọ ọn lọwọ, latari bo ṣe maa n ṣe pẹpẹfuru bii ẹlẹsin Musulumi ododo.

Muhammed ni iwadii ijinlẹ tawọn ọlọpaa-inu ṣe lati mọ ọna tawọn agbebọn naa n gba ri awọn nnkan ija oloro ti wọn n lo jẹ ki wọn dọdẹ obinrin yii, titi tọwọ fi ba a lọjọ kẹtala, oṣu Keji yii.

Wọn ni lasiko to n ko awọn nnkan ija to ba awọn afẹmiṣofo ra lati ilu Lafiya, nipinlẹ Nasarawa, wa si Zamfara ni wọn mu un.

Okoolelọọọdunrun ati marun-un ọta ibọn ni wọn ba lara ẹ, wọn ni inu bantẹ kan lo tọju ẹ pamọ si, o si ti da hijaabu awọkanlẹ bo o mọlẹ debi tẹnikan ko fi le fura pe o lẹbọ lẹru.

Nnkan kan ti wọn lo ṣe to daa ni pe gbara ti wọn mu un, ko la awọn agbofinro loogun rara to fi n ka boroboro nipa awọn iṣẹ laabi to ti ṣe. O lo ti pẹ toun ti n ba awọn afẹmiṣofo ṣiṣẹ, ti wọn si n san ẹtọ oun foun. O jẹwọ pe oun maa n sọpulai wọn ni ibọn, ọta ibọn ati kaadi SIM ti wọn ti rẹjista.

Eyi ni wọn fi tẹle e lọ sile ẹ, ti wọn si gbọn ọn yẹbẹyẹbẹ. Wọn ba awọn kaadi SIM Mtn ti wọn ti forukọ ẹ silẹ, awọn SIM naa si pọ gidi, o ju ẹgbẹrun kan lọ. Wọn beere ibi to ti n ra a, lo ba mu wọn lọ sọdọ ẹni ti to maa n ba a rẹjista awọn SIM naa fun un, wọn si fi pampẹ ọba gbe onitọhun.

Bi wọn ṣe wi, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii. Wọn ni gbogbo wọn maa foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply