Tinubu wọle ni ibudo idibo Gomina Makinde l’Ọyọọ

Ọrẹoluwa Adedeji

Aṣiwaju Bọla Tinubu ti i ṣe oludije lẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ni ibudo idibo Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde.

Ni ibudo idibo rẹ to wa ni Yuniiti kin-in-ni, Wọọdu keji, nijọba ibilẹ Ila Oorun Ibadan, iyẹn Ibadan North East to wa ni Abayọmi, Iwo Road, ni ẹgbẹ APC ti fagba han PDP ati ẹgbẹ oṣelu Labour.

Ninu esi idibo ti awọn to mojuto eto idibo lagbegbe naa ka jade, Tinubu ni ibo mẹrinlelọgọrun-un (104), nigba ti oludije ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, to wa ni ipo keji ni ibo mẹrinlelọgọrin (84). Ibo mẹtadinlọgbọn pere ni oudije lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ni.

Tẹ o ba gbagbe, ki eto idibo yii to waye, Gomina ipinlẹ

Ipinlẹ Ọyọ ti ṣeleri pe awọn ko ni i ṣatilẹyin fun Atiku nitori wahala to su yọ ninu ẹgbẹ naa lori alaga ẹgbẹ wọn to wa lati apa Oke-Ọya ti Atiku naa ti wa.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo n ṣejọba nipinlẹ Ọyọ, niṣe ni ẹgbẹ naa fidi rẹmi ni ibudo idibo gomina ipinlẹ naa.

Leave a Reply